Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọni pé inú ọkàn wa ni Ìjọba Ọlọ́run wà. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìjọ Southern Baptist Convention polongo pé Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kí “Ọlọ́run máa jọba lọ́kan èèyàn àti nínú ayé ẹni náà.” Póòpù Benedict XVI sọ ohun tó jọ èyí nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ Jesus of Nazareth, ó ní “Ìjọba Ọlọ́run máa dé sínú ayé ẹnì tó bá gba Jésù tó sì ní ìgbàgbọ́.”