Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Bí àpẹẹrẹ, ìgbìmọ̀ tó ń ṣojú fún àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kéde lọ́dún 1918 pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló máa di “ètò ìṣèlú tí Ọlọ́run máa lò láti ṣèjọba lórí ilẹ̀ ayé.” Lọ́dún 1965, àwọn tó ń ṣojú fún ìsìn Búdà, ẹ̀sìn Kátólíìkì, ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì, ẹ̀sìn Híńdù, Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù, àti Pùròtẹ́sítáǹtì pé jọ sí ìlú San Francisco láti gbàdúrà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, kí wọ́n sì tì í lẹ́yìn. Bákan náà lọ́dún 1979, Póòpù John Paul Kejì sọ pé òun ní ìrètí pé àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ló máa mú kí àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo fẹsẹ̀ múlẹ̀.”