Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “ìràpadà” máa ń tọ́ka sí iye kan tàbí ohun iyebíye kan tẹ́nì kan san. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ Hébérù náà ka·pharʹ túmọ̀ sí “bò.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Ó sábà máa ń tọ́ka sí bíbo ẹ̀ṣẹ̀. (Sáàmù 65:3) Ọ̀rọ̀ míì tó jẹ mọ́ ọn ni koʹpher, ohun tíyẹn máa ń tọ́ka sí ni iye tí wọ́n san láti bo ẹ̀ṣẹ̀ ẹnì kan tàbí tú u sílẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:30) Bákan náà, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà lyʹtron sábà máa ń túmọ̀ sí “ìràpadà,” wọ́n sì lè túmọ̀ rẹ̀ sí “owó ìtúsílẹ̀.” (Mátíù 20:28; Bíbélì The New Testament in Modern Speech, by R. F. Weymouth) Àwọn òǹkọ̀wé tó jẹ́ Gíríìkì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà tí wọ́n bá ń tọ́ka sí owó tẹ́nì kan san kí wọ́n lè tú ẹrú sílẹ̀ tàbí ra ẹni tí wọ́n mú lẹ́rú nígbà ogun pa dà.