Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
a Ìlú Bábílónì àtijọ́ ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn àti àtúnwáyé ti ṣẹ̀ wá. Nígbà tó yá, àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí nílẹ̀ Íńdíà gbé òfin Kámà kalẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Britannica Encyclopedia of World Religions sọ pé ohun tí òfin Kámà túmọ̀ sí ni “àṣesílẹ̀-làbọ̀wábá, ìyẹn ni pé téèyàn bá ṣe ohun kan nígbà tó wà láyé báyìí, ó máa jìyà rẹ̀ tó bá tún ayé wá.”—Ojú ìwé 913.