Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Òfin àwọn Júù ò fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fi Tórà kọ́ àwọn obìnrin, èyí sì ta ko ohun tí Tórà fúnra rẹ̀ sọ. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Míṣínà sọ ohun tí Rábì Eliezer ben Hyrcanus sọ, pé: “Tẹ́nì kan bá fi Tórà kọ́ ọmọ rẹ̀ obìnrin, bí ẹni kọ́ ọ ní ìwàkiwà ló rí.” (Sotah 3:4) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún wà nínú ìwé Támọ́dì ti Jerúsálẹ́mù, pé: “Ó sàn ká dáná sun Tórà ju ká fi kọ́ àwọn obìnrin.”—Sotah 3:19a.