Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
c Lórí ọ̀rọ̀ ààwẹ̀ ológójì [40] ọjọ́ táwọn èèyàn máa ń pè ní Lẹ́ńtì, ìwé New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mẹ́ta àkọ́kọ́, ààwẹ̀ tí wọ́n máa ń gbà kí wọ́n tó ṣe ọdún àjíǹde [Easter] kì í kọjá ọ̀sẹ̀ kan, ìgbà míì kì í ju ọjọ́ méjì lọ. . . . Nínú òfin karùn-ún ti Council of Nicaea (325), la ti kọ́kọ́ gbọ́ ogójì [40] ọjọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ò gbà pé ọ̀rọ̀ Lẹ́ńtì ni wọ́n ń sọ níbẹ̀.”—Ẹ̀dà Kejì, Ìdìpọ̀ 8, ojú ìwé 468.