Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé
b Nígbà tí Jèhófà ń bá Jóòbù sọ̀rọ̀, ó lo àfiwé tààràtà, nígbà míì sì rèé, ó lo àwọn ọ̀rọ̀ ewì. Jèhófà lo àwọn ọ̀nà yìí lọ́nà tó dáa gan-an débi pé èèyàn ò ní tètè mọ̀ tó bá yí kúrò lórí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kan bọ́ sí òmíì. (Bí àpẹẹrẹ, wo, Jóòbù 41:1, 7, 8, 19-21.) Èyí ó wù kí Jèhófà lò nínú ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ kó lè túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá.