ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
    Jí!—2016 | No. 4
    • Obìnrin kan ń wo tẹlifíṣọ̀n, ó sì ń jẹ oúnjẹ pàrùpárù

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

      Àwọn Àṣà Tó Lè Ṣe Ẹ́ Láǹfààní

      • Aago tó ní àláàmù

        AUSTIN ṣì ń sùn nígbà tí aago rẹ̀ dún. Àmọ́, ó dìde kánmọ́ lórí bẹ́ẹ̀dì, ó wọṣọ tó fi ń ṣeré ìmárale tó ti kó sílẹ̀ láti alẹ́ àná, ó sì jáde lọ sáré, bó ti máa ń ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀ láti bí ọdún kan sẹ́yìn.

      • Àpò súìtì kan

        Laurie ṣẹ̀ṣẹ̀ bá ọkọ rẹ̀ jà tán ni. Ló bá fi ìbínú lọ sílé ìdáná, ó gbé odindi ṣokoléètì kan, ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ tán, bó ṣe máa ń ṣe ní gbogbo ìgbà tínú bá ti bí i.

      Kí ni Austin àti Laurie fi jọra? Yálà wọ́n mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀, àwọn méjèèjì ló ní àṣà kan tó ti mọ́ wọn lára.

      Ìwọ ńkọ́? Ṣé àwọn nǹkan dáadáa kan wà tó wù ẹ́ láti máa ṣe? Bíi ṣíṣe eré ìmárale déédéé, kó o túbọ̀ máa rí oorun sùn, tàbí kó o túbọ̀ máa ráyè fáwọn tó o fẹ́ràn.

      Lọ́wọ́ kejì, ó lè wù ẹ́ láti jáwọ́ nínú àṣà tí kò tọ́, irú bíi mímu sìgá, jíjẹ́ àwọn oúnjẹ pàrùpárù tàbí lílo àkókò tó pọ̀ jù lórí fóònù.

      Ká sòótọ́, ó lè má rọrùn láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò dáa. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé ohun tí kò dáa ló máa ń rọrùn láti ṣe, wẹ́rẹ́ ló máa ń mọ́ọ̀yàn lára, àmọ́ àtijáwọ́ á wá dogun!

      Tóò, báwo wá la ṣe lè borí àwọn àṣà tí kò dáa, ká sì fi èyí tó dáa rọ́pò wọn? Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Bíbélì mẹ́ta tó máa ràn wá lọ́wọ́.

  • 1 Má Tan Ara Rẹ
    Jí!—2016 | No. 4
    • Obìnrin tó ń kọ̀wé

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

      1 Má Tan Ara Rẹ

      Ó sábà máa ń wù wá láti ṣe gbogbo àtúnṣe tó yẹ nígbèésí ayé wa lẹ́ẹ̀kan náà. Nígbà míì, èèyàn lè sọ pé, ‘Lọ́sẹ̀ yìí, mi ò ní mu sìgá mọ́, mi ò ní ṣépè mọ́, mi ò ní pẹ́ kí n tó lọ sùn, màá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré ìmárale, màá máa jẹun gidi, màá sì máa pe àwọn òbí mi àgbà.’ Tó o bá gbìyànjú láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń lé eku méjì, o ò wá ní rí ìkankan ṣe!

      ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—Òwe 11:2.

      Ẹni tó jẹ́ amẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ohun tí agbára òun gbé. Ó mọ̀ pé ó ní ìwọ̀nba nǹkan tí òun lè fi àkókò, okun àti ohun ìní òun ṣe. Torí náà, dípò tí á fi máa fẹ́ láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, díẹ̀díẹ̀ ni á máa ṣe é.

      Tó o bá gbìyànjú láti ṣe gbogbo àtúnṣe yìí lẹ́ẹ̀kan náà, ńṣe lo máa dà bí ẹni tó ń lé eku méjì, o ò wá ní rí ìkankan ṣe!

      OHUN TÓ O LÈ ṢE

      Díẹ̀díẹ̀ ni kó o máa ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ. Àwọn àbá yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́:

      1. Wá ìwé méjì, kọ àwọn ìwà rere tó o fẹ́ máa hù sínú ọ̀kan, kó o sì kọ àwọn àṣà tí ò dáa tó o fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ sínú ìkejì. Kọ gbogbo ohun tó o fẹ́ ṣe lórí apá méjèèjì láìṣẹ́ ku ohunkóhun.

      2. Èyí tó o kọ́kọ́ fẹ́ ṣe ni kó o kọ ṣáájú nínú gbogbo rẹ̀.

      3. O lè kọ́kọ́ mú àṣà kan tàbí méjì nínú ìwé méjèèjì, ìyẹn sì ni kó o gbájú mọ́. Tó bá tún yá, mú méjì míì tí wàá tún ṣiṣẹ́ lé lórí.

      Ohun tó máa jẹ́ kí àtúnṣe náà yára ni pé kó o fi àwọn àṣà tó dáa rọ́pò èyí tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé àwòjù tẹlifíṣọ̀n wà lára àṣà tó o fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀, tó sì tún wù ẹ́ láti máa wáyè fáwọn èèyàn rẹ, o lè pinnu pé: ‘Dípò kí n gba ìdí tẹlifíṣọ̀n lọ ní gbàrà tí mo délé, màá kúkú fóònù àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn ẹbí mi.’

      ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

      “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—Fílípì 1:10.

      “Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ.”​—Oníwàásù 7:8.

  • 2 Kíyè Sí Ohun Tó Ń Lọ Láyìíká Rẹ
    Jí!—2016 | No. 4
    • Aṣọ eré ìmárale, bàtà, ike omi, àti kọ̀ǹpútà kékeré tí wọ́n gbé kalẹ̀ lálẹ́

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

      2 Kíyè Sí Ohun Tó Ń Lọ Láyìíká Rẹ

      • O pinnu pé wàá máa jẹun gidi síkùn, ṣùgbọ́n àwọn oúnjẹ pàrùpárù ṣì kún inú ilé rẹ.

      • O pinnu pé o ò ní fa sìgá mọ́, síbẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣì tún ń fi sìgá lọ̀ ẹ́.

      • O ti pinnu pé wàá ṣe eré ìmárale lónìí, àmọ́ ojú ń ro ẹ́ láti ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá aṣọ tó o máa wọ̀!

      Ǹjẹ́ o rí ohun tó jọra nínú àwọn àpẹẹrẹ yìí? Ẹ̀rí ti fi hàn pé ohun tó wà ní àyíká wa àti àwọn tá à ń bá rìn ló máa ń pinnu bóyá a máa lè ní àṣà tó dáa, ká sì jáwọ́ nínú èyí tí kò dáa.

      ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.

      Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ronú nípa àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá lè yẹra fún àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ àfojúsùn wa, àá sì lè máa ṣe ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́. (2 Tímótì 2:22) Ní kúkúrú, ọlọ́gbọ́n ni wá tá a bá ń kíyè sí ohun tó n lọ láyìíká wa.

      Yẹra fún nǹkan tó máa jẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa, mú kí ṣíṣe ohun tó tọ́ rọrùn fún ẹ

      OHUN TÓ O LÈ ṢE

      • Yẹra fún àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, rí i dájú pé o kò tọ́jú oúnjẹ pàrùpárù sílé. Ìyẹn ló máa jẹ́ kó o lè yẹra fún irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ tó bá wù ẹ́ láti jẹ ẹ́.

      • Mú kí ṣíṣe ohun tó tọ́ rọrùn fún ẹ. Ká sọ pé o ti pinnu pé o máa ṣe eré ìmárale tílẹ̀ bá mọ́, ńṣe ni kó o kó àwọn aṣọ tó o máa lò sítòsí kó o tó lọ sùn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa mú kó rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe láì lọ́ra.

      • Fara balẹ̀ yan àwọn tó o máa bá rìn. Kì í pẹ́ tá a fi máa ń mú ìwà àwọn ọ̀rẹ́ wa. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Torí náà, dín wọléwọ̀de rẹ kù pẹ̀lú àwọn tó máa mú kó o ṣì tún máa hùwà tí o kò fẹ́, kó o sì yan àwọn tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́rẹ̀ẹ́.

      ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

      “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”​—Òwe 13:20.

      “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”​—Òwe 21:5.

  • 3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ
    Jí!—2016 | No. 4
    • Obìnrin kan tó ń fàmì sára kàlẹ́ńdà

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ÀWỌN ÀṢÀ TÓ LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ

      3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Sú Ẹ

      Kàlẹ́ńdà tí wọ́n ti fàmì sí

      Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé ó máa ń gbà tó ọjọ́ mọ́kànlélógún [21] kí ìwà kan tó lè mọ́ọ̀yàn lára. Àmọ́ ká sòótọ́, ìwádìí fi hàn pé àwọn míì kì í pẹ́ tó bẹ́ẹ̀, àwọn míì sì máa ń pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ kí nǹkan tó mọ́ wọn lára. Ṣé ó wá yẹ kí èyí mú ọ rẹ̀wẹ̀sì?

      Ronú nípa àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ó wù ẹ́ láti máa ṣe eré ìmárale nígbà mẹ́ta lọ́sẹ̀.

      • Lọ́sẹ̀ àkọ́kọ́, ó ṣe dáadáa.

      • Lọ́sẹ̀ kejì, o pa ọjọ́ kan jẹ.

      • Lọ́sẹ̀ kẹta, o tún ṣe dáadáa.

      • Lọ́sẹ̀ kẹrin, ekukáká ló fi ṣe é lọ́jọ́ kan.

      • Lọ́sẹ̀ karùn-ún, o tún ṣe dáadáa, látìgbà yẹn lọ o kò pa ọjọ́ kankan jẹ mọ́.

      Ó gba ọ̀sẹ̀ márùn-ún kí àṣà tuntun náà tó mọ́ ẹ lára. Ó lè jọ pé ó pẹ́ gan-an kó tó mọ́ ẹ lára, àmọ́ inú rẹ á dùn pé ọwọ́ rẹ ti tẹ ohun tó o fẹ́.

      ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Olódodo lè ṣubú ní ìgbà méje pàápàá, yóò sì dìde dájúdájú.”​—Òwe 24:16.

      Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe jẹ́ kó sú wa. Kì í ṣe iye ìgbà tá a ṣubú ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe iye ìgbà tá a pa dà dìde.

      Kì í ṣe iye ìgbà tá a ṣubú ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe iye ìgbà tá a pa dà dìde

      OHUN TÓ O LÈ ṢE

      • Má ṣe parí èrò sí pé o ti di aláṣetì torí pé ọwọ́ rẹ kò tètè tẹ ohun tó o fẹ́. Wàá máa rí ìfàsẹ́yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bó o ṣe ń sapá láti lé àfojúsùn rẹ bá.

      • Ìgbà tí nǹkan lọ bó o ṣe fẹ́ ni kó o máa rò. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe lo fẹ́ mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ dára sí i, bí ara rẹ pé: ‘Ìgbà wo ló ṣe mí bíi kí n jágbe mọ́ àwọn ọmọ mi, àmọ́ tí mi ò ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni mo ṣe dípò ìyẹn? Báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà míì?’ Irú àwọn ìbéèrè báyìí máa jẹ́ kó o lè ronú lórí àwọn àṣeyọrí rẹ dípò àwọn ìfàsẹ́yìn tó o ní.

      Ṣé o fẹ́ mọ àwọn ọ̀nà míì tí Bíbélì lè gbà ràn ẹ́ lọ́wọ́, bóyá láti borí àníyàn, bí ìdílé rẹ ṣe lè láyọ̀, àti bó o ṣe lè ní ayọ̀ tó jinlẹ̀? Bá ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org.

      ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ MÍÌ

      “Ní ti ojú rẹ, ọ̀kánkán tààrà ni kí ó máa wò.”​—Òwe 4:25.

      “Èmi a máa gbàgbé ohun gbogbo tí ó ti kọjá, èmi a sì máa nàgà láti mú ohun tí ó wà níwájú. Mò ń làkàkà láti dé òpin iré-ìje mi.”​—Fílípì 3:13, 14, Bibeli Ìròyìn Ayọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́