ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g17 No. 5 ojú ìwé 14-15
  • Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan
  • Jí!—2017
Jí!—2017
g17 No. 5 ojú ìwé 14-15
Astana, Kazakhstan

City of Astana

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ẹ Jẹ́ Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

Àwòrán orílẹ̀-èdè Kazakhstan

DARANDARAN ni ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú yìí. Títí dí òní àwọn èèyàn ilẹ̀ yìí máa ń kó ẹran wọn jẹ̀ kiri bí ojú ọjọ́ bá ṣe gbà. Nígbà ooru, wọ́n máa ń daran lọ sí orí àwọn òkè tó tutù. Tó bá sì di ìgbà òtútù, wọ́n máa da àwọn ẹran wọn wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.

Inú ìlú ńlá ni àwọn kan ń gbé. Síbẹ̀, èèyàn á rí i lára wọn pé wọn kò gbàgbé ìgbésí ayé darandaran tí àwọn baba ńlá wọn gbé. Èyí hàn nínú àṣà wọn, oúnjẹ wọn àti iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n ń ṣe. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Kazakhstan máa ń gbádùn ewì tó dùn, orin àti àwọn orin tí wọ́n fi ohun èlò orin ìbílẹ̀ wọn kọ.

Ilé tí wọ́n máa ń gbé rí roboto, kì í sì tóbi púpọ̀, àwọn èèyàn sọ pé àwọn tó ń gbé irú ilé yìí máa ń mọyì ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó wà láàárín wọn fẹ́ràn ilé náà, àwọn tó ń gbé inú ìlú ńlá láàárín wọn sì sábà máa ń lo irú ilé bẹ́ẹ̀ fún ayẹyẹ pàtàkì. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ pàápàá fẹ́ràn láti máa dé sínú ilé yìí. Inú ilé wọn máa ń kún fún àwọn aṣọ aláràbarà tí àwọn obìnrin wọn hun tí wọ́n sì fi tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì sílẹ̀ tàbí sára ògiri wọn.

Ìdílé kan wà nínú ilé wọn tó rí roboto

Nínú ilé wọn

Àwọn tó ń gbé lábúlé nínú wọn fẹ́ràn ẹṣin púpọ̀. Ó kéré tán, wọ́n ní orúkọ mọ́kànlélógún [21] tí wọ́n fi ń pe ẹṣin, tó ní oríṣiríṣi ìtumọ̀ tó jinlẹ̀. Wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ tó ju ọgbọ̀n [30] lọ tí wọ́n fi ń ṣàlàyé àwọ̀ tí ẹṣin ní. Ẹ̀bùn ńlá tó jọjú gbáà ni tí wọ́n bá fún ẹnì kan lẹ́ṣin. Àti kékeré ni àwọn ọmọkùnrin wọn ti máa ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń gun ẹṣin.

Oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn kì í ta lẹ́nu, ó sì máa ń ní ẹran nínú dáadáa. Koumiss ni wọ́n máa ń mu, wàrà ẹṣin ni wọ́n fi ṣe é, wọ́n sì gbà pé ó ń ṣara lóore gan-an. Wọ́n tún máa ń mu shubat tó kan díẹ̀ lẹ́nu, wàrà ràkúnmí ni wọ́n fi ṣe ìyẹn.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Almaty kí àwọn alèjò káàbọ̀ láti rìn yíká ọgbà náà.

Àmọ̀tẹ́kùn orí yìnyín

Àmọ̀tẹ́kùn orí yìnyín máa ń wà ní orí àwọn òkè Kazakhstan nígbà ẹ̀ẹ̀rùn

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Ó kéré tán oríṣi òdòdó mẹ́rìndínlógójì [36] ló wà ní orílẹ̀-èdè Kazakhstan, àwòrán bí àwọn òdòdó yẹn ṣe rí ló sì pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀.

Ìlà oòrùn omi odò Balkhash tó wà ní Kazakhstan ní iyọ̀ nínú àmọ́ ní apá ìwọ̀ oòrùn rẹ̀, kò ní iyọ̀ nínú.

Ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn Kazakhstan láti máa lo ẹyẹ idì fi ṣọdẹ. Wọ́n gbóná nínú kíkọ́ ẹyẹ náà láti ṣọdẹ.

Ẹyẹ idì tó ní ẹ̀rọ tí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn èèyàn máa bà á bà lé apá ẹnì kan

Ohun tí wọ́n fi sí orí ẹyẹ idì yìí kò ní jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn èèyàn máa bà á

  • ÈDÈ WỌN: KAZAKH, RUSSIAN

  • IYE ÈÈYÀN: 17,563,000

  • OLÚ ÌLÚ: ASTANA

  • OJÚ ỌJỌ́: Ó MÁA Ń GBÓNÁ NÍGBÀ Ẹ̀Ẹ̀RÙN, YÌNYÍN SÌ MÁA Ń JÁ BỌ́ NÍGBÀ ÒTÚTÙ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́