ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
    • kọ́kọ́ máa sọ dáadáa. Gbólóhùn kúkúrú, tó rọrùn ló sábà máa ń dára jù lọ. Bó bá jẹ́ inú ìjọ lo ti fẹ́ sọ̀rọ̀ yìí, o lè kọ gbólóhùn wọ̀nyẹn sílẹ̀ tàbí kí o tiẹ̀ há wọn sórí kí àwọn gbólóhùn tí o máa kọ́kọ́ sọ lè nípa lórí àwùjọ tó bó ṣe yẹ. Bí o bá fara balẹ̀ sọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láìkánjú, ó lè jẹ́ kí o fọkàn balẹ̀ sọ ìyókù ọ̀rọ̀ rẹ bó ṣe yẹ.

      Ìgbà Tó Yẹ Kí O Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀. Ẹnu ò kò lórí ìgbà tó yẹ kéèyàn múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀. Àwọn kan tó ti pẹ́ lẹ́nu ọ̀rọ̀ sísọ gbà pé orí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ló yẹ kéèyàn ti bẹ̀rẹ̀ ìmúra ọ̀rọ̀ sísọ. Èrò ti àwọn mìíràn tó dìídì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí èèyàn ṣe máa ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ni pé ìgbà tí èèyàn bá múra àárín ọ̀rọ̀ tán ló yẹ kó ṣẹ̀ṣẹ̀ tó múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀.

      Ó dájú pé o ní láti mọ kókó tí o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí àti àwọn kókó tí o fẹ́ ṣàlàyé kí o tó lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá a mu. Àmọ́, bó bá wá jẹ́ ìwé àsọyé tí a ti tẹ̀ lo fẹ́ lò ńkọ́? Tí o bá ka ìwé àsọyé tán, tí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan sọ sí ọ lọ́kàn, kò burú rárá tí o bá kọ ọ́ sílẹ̀. Àmọ́ má ṣe gbàgbé o, kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó lè múná dóko, o ní láti ronú nípa àwùjọ àti ohun tó wà nínú ìwé àsọyé rẹ pẹ̀lú.

  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
    • Ẹ̀KỌ́ 39

      Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko

      Kí ló yẹ kí o ṣe?

      Nígbà tí o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ, ó yẹ kí o dìídì sọ nǹkan kan tí yóò sún àwùjọ láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.

      Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

      Ohun téèyàn bá sọ níparí ọ̀rọ̀ ló sábà máa ń pẹ́ jù lọ́kàn àwùjọ. Ó máa nípa lórí bí gbogbo ohun tá a sọ ṣe máa ṣàṣeyọrí tó.

      Ó ṢEÉ ṣe kí o ti fara balẹ̀ ṣèwádìí kí o sì ti ṣètò àlàyé àárín ọ̀rọ̀ rẹ dáadáa. O tún lè ti ṣètò ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ń múni nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀. Síbẹ̀, ó ṣì ku ohun kan, ohun náà sì ni ìparí ọ̀rọ̀ tó múná dóko. Má fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un o. Ohun tó o sọ kẹ́yìn ló sábà máa ń pẹ́ lọ́kàn àwọn èèyàn jù lọ. Bí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ kò bá lè súnni ṣiṣẹ́ kò ní jẹ́ kí gbogbo àlàyé àtẹ̀yìnwá tí o ti ń ṣe bọ̀ múná dóko.

      Kíyè sí ohun tó tẹ̀ lé e yìí: Lápá ìgbẹ̀yìn ayé Jóṣúà, ó sọ àsọyé mánigbàgbé kan fún àwọn àgbà ọkùnrin orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Jóṣúà mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti ń gbà bá Ísírẹ́lì lò bọ̀ láti ìgbà ayé Ábúráhámù, ṣe ó kàn tún àwọn kókó pàtàkì sọ gẹ́gẹ́ bí ẹni ń ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi tinútinú rọ àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́.” Fúnra rẹ ka ìparí ọ̀rọ̀ Jóṣúà yìí nínú Jóṣúà 24:14, 15.

      Ọ̀rọ̀ pàtàkì mìíràn wà nínú Ìṣe 2:14-36, èyí tí àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwùjọ kan ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ó kọ́kọ́ ṣàlàyé fún wọn pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jóẹ́lì sọ nípa bí Ọlọ́run yóò ṣe tú ẹ̀mí rẹ̀ lé àwọn kan lórí ni wọ́n rí tó ń ṣẹ yìí. Ó wá sọ bí èyí ṣe kan àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tí ìwé Sáàmù sọ nípa ti àjíǹde Jésù Kristi àti nípa bí a ṣe máa gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ní ìparí ọ̀rọ̀, Pétérù sọ ojú abẹ níkòó fún àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Ó sọ ohun pàtàkì tí ń bẹ níwájú gbogbo wọn. Ó ní: “Nítorí náà, kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” Àwọn tó wà níbẹ̀ wá béèrè pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, kí ni kí àwa ṣe?” Pétérù bá fèsì pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi.” (Ìṣe 2:37, 38) Lọ́jọ́ yẹn, ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn lára àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ló tẹ́wọ́ gba òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù Kristi.

      Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Fi Sọ́kàn. Ó yẹ kí ohun tó o bá sọ níparí ọ̀rọ̀ rẹ wé mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ ní tààràtà. Ó ní láti jẹ́ ibi tó yẹ kí àlàyé àwọn kókó tó o

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́