ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
    • Obìnrin kan ń mú Bíbélì látinú ibi ìkówèésí rẹ̀

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

      Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ka Bíbélì?

      “Èrò mi ni pé ó máa ṣòro fún mi láti lóye Bíbélì.”​—Jovy

      “Mo ronú pé kíka Bíbélì kì í gbádùn mọ́ni.”​—Queennie

      “Nígbà tí mo bá rí bí Bíbélì ṣe tóbi tó, ńṣe ló máa ń sú mi.”​—Ezekiel

      Ṣé o ti ronú nípa kíka Bíbélì, àmọ́ tí o kò kà á torí pé o ní irú èrò tí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí ní? Kíka Bíbélì máa ń ka ọ̀pọ̀ èèyàn láyà. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì lè jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè láyọ̀, kó o sì máa gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀? Tó o bá wá mọ̀ pé àwọn ọ̀nà kan wà tó o lè gbà kà á, tí wàá sì gbádùn ẹ̀ ńkọ́? Ṣé wàá fẹ́ láti gbìyànjú ẹ̀ wò, kó o sì rí ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú kíka Bíbélì?

      Àwọn kan ti ka Bíbélì, ó sì ti ṣe wọ́n láǹfààní. Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọn sọ.

      Ezekiel, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo dà bí ẹni tó ń wa mọ́tò láìjẹ́ pé ó ní ibi kan lọ́kàn tó fẹ́ lọ. Ṣùgbọ́n kíka Bíbélì ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ ní ìtúmọ̀. Ó ní àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí mo lè máa lò lójoojúmọ́.”

      Frieda, tí òun náà ti lé lọ́mọ ogún [20] ọdún, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, ńṣe ni mo máa kanra lódìlódì. Àmọ́ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, mo tí mọ bí mo ṣe lè kápá rẹ̀. Ní báyìí, àwọn èèyàn ti ń sún mọ́ mi, mo sì ti láwọn ọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí i.”

      Obìnrin kan tó ń jẹ́ Eunice tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún, sọ nípa Bíbélì pé, “Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìwà tó dáa.”

      Bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí àti ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì, kíka Bíbélì lè ran ìwọ náà lọ́wọ́ láti gbádùn ìgbésí ayé rẹ. (Aísáyà 48:​17, 18) Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Bíbélì lè ṣe fún ẹ, lára wọn ni (1) ṣíṣe ìpinnu tó tọ́, (2) yíyan ọ̀rẹ́ tòótọ́, (3) fífara da ìdààmú, (4) èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, wàá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni gbogbo ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ti wá, torí náà o kò ní kọsẹ̀ tó o bá fi wọ́n sílò. Ọlọ́run kò lè fún wa ní ìmọ̀ràn burúkú.

      Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì. Àmọ́, kí làwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bẹ̀rẹ̀, kó o sì gbádùn rẹ̀?

  • Ibo Ni Mo Ti Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
    • KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

      Ibo Ni Mo Ti Fẹ́ Bẹ̀rẹ̀?

      Obìnrin tó ń gbàdúrà kó tó bẹ̀rẹ̀ síní ka Bíbélì

      Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo lè gbé táá jẹ́ kó o gbádùn Bíbélì kíkà, kó o sì jàǹfààní nínú rẹ̀? Wo àwọn àbá márùn-ún yìí tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́.

      Jẹ́ kí ibi tó o wà tù ẹ́ lára. Wá ibi tó pa rọ́rọ́, kó o sì dín ohun tó lè pín ọkàn rẹ níyà kù, kó o lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ò ń kà. Ó tún ṣe pàtàkì pé kí ìmọ́lẹ̀ àti afẹ́fẹ́ tó tura wà níbẹ̀, kí ohun tí ò ń kà lè wọ̀ ẹ́ lọ́kàn.

      Ní èrò tó tọ́. Ọ̀dọ̀ Baba wa ọ̀run ni Bíbélì ti wá, torí náà kó o lè jàǹfààní nínú rẹ̀, á dára kó o ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ bí ọmọdé tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tó o bá ti ní èrò òdì nípa Bíbélì tẹ́lẹ̀, o ní láti gbé èrò náà tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, kí Ọlọ́run lè kọ́ ẹ.​—Sáàmù 25:4.

      Kọ́kọ́ Gbàdúrà. Èrò Ọlọ́run ló wà nínú Bíbélì, ìdí nìyẹn tá a fi nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ká lè lóye ohun tí à ń kà. Ọlọ́run ti ṣèlérí láti “fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ yìí lè mú kó o mọ èrò Ọlọ́run lórí àwọn nǹkan. Tó bá yá, ẹ̀mí mímọ́ á ṣí ọkàn rẹ payá láti mọ “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”​—1 Kọ́ríńtì 2:10.

      Kà á lọ́nà tó fi máa yé ẹ. Má kàn máa ka Bíbélì lọ gbuurugbu. Máa dánu dúró kó o lè ronú lórí ohun tó o kà. Bí ara rẹ láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ẹ̀kọ́ wo ni mo kọ́ lára ẹni tí mò ń kà nípa rẹ̀ yìí? Báwo ni mo ṣe lè fi ẹ̀kọ́ náà sílò nígbèésí ayé mi?’

      Ní àfojúsùn kan. Kí Bíbélì kíkà tó lè ṣe ẹ́ láǹfààní, o yẹ kó o ní ohun kan lọ́kàn tó o fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó máa wúlò fún ẹ nígbèésí ayé. O lè fi ṣe àfojúsùn rẹ pé: ‘Mo fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run fúnra rẹ̀.’ ‘Mo fẹ́ túbọ̀ ní ìwà tó dáa, táá jẹ́ kí n jẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó rere.’ Lẹ́yìn náà, yan ẹsẹ Bíbélì tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí kókó náà.a

      Àwọn àbá márùn-ún tá a ti jíròrò yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, báwo lo ṣe lè mú kí Bíbélì kíkà náà gbádùn mọ́ ẹ? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣèrànwọ́.

      a Tí o kò bá mọ ẹsẹ Bíbélì tó o máa kà lórí kókó kàn, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

      BÓ O ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ PÚPỌ̀ SÍ I

      • Fara balẹ̀, kó o má sì kánjú

      • Jẹ́ kí ohun tí ò ń kà jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ​—fọkàn yàwòrán pé o wà níbẹ̀

      • Gbìyànjú láti wo bí àwọn ẹsẹ náà ṣe bára mu

      • Wo ẹ̀kọ́ tó wà nínú ibi tó o kà

  • Báwo Ni Mo Ṣe Máa Gbádùn Ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
    • Obìnrin kan ń lo ohun tó lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tó ń ka Bíbélì

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

      Báwo Ni Mo Ṣe Máa Gbádùn Ẹ̀?

      Ṣé kíka Bíbélì máa ń gbádùn mọ́ni? Àǹfààní wo lo sì máa rí níbẹ̀? Ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí sinmi lórí ọ̀nà tí ò ń gbà ka Bíbélì. Jẹ́ ká wo ohun tó o lè ṣe láti mú kí Bíbélì máa wù ẹ́ kà, kó o sì gbádùn rẹ̀.

      Lo Bíbélì tó dáa, tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì bágbà mu. Tó o bá ka Bíbélì tí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣòro láti lóye tàbí tí kò bágbà mu, oò ní gbádùn ohun tí ò ń kà nínú rẹ̀. Torí náà, Bíbélì tó máa tètè yé ẹ táwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì máa wọ̀ ẹ́ lọ́kàn ni kó o lò. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ Bíbélì tí wọ́n fara balẹ̀ túmọ̀, tí ìtúmọ̀ rẹ̀ sì péye.a

      Lo ohun èlò ìgbàlódé. Lóde òní, kì í ṣe orí ìwé nìkan la ti lè rí Bíbélì kà, a tún lè wà á jáde sórí fóònù, tablet tàbí kọ̀ǹpútà, ká sì máa kà á látibẹ̀. Àwọn Bíbélì orí ẹ̀rọ kan tiẹ̀ wà tó tún máa fún ẹ láǹfààní láti wo ẹsẹ Bíbélì kan tàbí kókó ọ̀rọ̀ kan nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì míì kó o lè fi wọ́n wéra. Tó bá jẹ́ pé èyí tó o lè tẹ́tí sí ló rọ̀ ẹ́ lọ́rùn, Bíbélì tí wọ́n ti kà sílẹ̀ tún wà tó o lè máa gbọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn gbádùn kí wọ́n máa tẹ́tí sí Bíbélì tí wọ́n ti kà sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú mọ́tò, tí wọ́n ń fọṣọ, tàbí tí wọ́n ń ṣe àwọn nǹkan míì tó gbà wọ́n láyè láti máa fetí sílẹ̀. Oò ṣe gbìyànjú èyí tó máa rọrùn fún ẹ nínú àwọn àbá yìí?

      Lo ohun tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ohun tó o lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí máa jẹ́ kó o túbọ̀ jàǹfààní nínú kíka Bíbélì. O lè lo àwòrán àwọn ilẹ̀ tí wọ́n dárúkọ nínú Bíbélì, èyí máa jẹ́ kó o rí àwọn ibi tí Bíbélì mẹ́nu kàn, wàá sì lè fọkàn yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ bí èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí tàbí àwọn tó wà ní apá tá a pè ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” lórí ìkànnì jw.org, máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí àwọn apá kan nínú Bíbélì túmọ̀ sí.

      Lo onírúurú ọ̀nà. Tí kíka Bíbélì láti páálí dé páálí bá jọ pé ó kà ẹ́ láyà, o lè bẹ̀rẹ̀ nípa kíka àwọn apá tó gbádùn mọ́ ẹ jù lọ. Tó o bá fẹ́ mọ ìtàn àwọn èèyàn tó lókìkí nínú Bíbélì, o lè ka àwọn apá Bíbélì tó dá lórí ìtàn àwọn èèyàn. A sọ ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe é nínú àpótí tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìyẹn àpótí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mọ Àwọn Èèyàn Tí Bíbélì Sọ̀rọ̀ Nípa Wọn.” O sì tún lè ka onírúurú ìtàn tó wà nínú Bíbélì tàbí bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra. Oò ṣe gbìyànjú ọ̀kan lára àwọn àbá náà?

      a Ọ̀pọ̀ ti rí i pé Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun péye, ó ṣeé gbára lé, ó sì rọrùn láti kà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ Bíbélì yìí, ó sì wà ní èdè tó lé ní àádóje [130]. O lè wa Bíbélì yìí jáde lórí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o wa JW Library jáde láti play store sorí fóònù rẹ. Tó o bá sì fẹ́, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè mú èyí tá a tẹ̀ jáde wá fún ẹ nílé.

      MỌ ÀWỌN ÈÈYÀN TÍ BÍBÉLÌ SỌ̀RỌ̀ NÍPA WỌN

      Díẹ̀ lára àwọn obìnrin olóòótọ́

      Ábígẹ́lì

      1 Sámúẹ́lì orí 25

      Ẹ́sítérì

      Ẹ́sítérì orí 2-5, 7-9

      Hánà

      1 Sámúẹ́lì orí 1-2

      Màríà

      (ìyá Jésù) Mátíù orí 1-2; Lúùkù orí 1-2; tún wo Jòhánù 2:​1-12; Ìṣe 1:​12-14; 2:​1-4

      Ráhábù

      Jóṣúà orí 2, 6; tún wo Hébérù 11:​30, 31; Jákọ́bù 2:​24-26

      Rèbékà

      Jẹ́nẹ́sísì orí 24-27

      Sárà

      Jẹ́nẹ́sísì orí 17-18, 20-21, 23; tún wo Hébérù 11:11; 1 Pétérù 3:​1-6

      Díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin tó tayọ

      Ábúráhámù

      Jẹ́nẹ́sísì orí 11-24; tún wo orí 25:​1-11

      Dáfídì

      1 Sámúẹ́lì orí 16-30; 2 Sámúẹ́lì orí 1-24; 1 Àwọn Ọba orí 1-2

      Jésù

      Ìwé Ìhìn Rere Mátíù, Máàkù, Lúùkù, àti Jòhánù

      Mósè

      Ẹ́kísódù orí 2-20, 24, 32-34; Númérì orí 11-17, 20, 21, 27, 31; Diutarónómì orí 34

      Nóà

      Jẹ́nẹ́sísì orí 5-9

      Pọ́ọ̀lù

      Ìṣe orí 7-9, 13-28

      Pétérù

      Mátíù orí 4, 10, 14, 16-17, 26; Ìṣe orí 1-5, 8-12

      ÀWỌN OHUN ÈLÒ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TÁWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ṢE

      • JW.ORG​—Ìkànnì yìí ní ọ̀pọ̀ ohun èlò téèyàn lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, irú bí apá tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ.” Ó tún ní ìtọ́ni lórí bá a ṣe lè wa ètò ìṣiṣẹ́ JW Library jáde

      • Wo Ilẹ̀ Dáradára Náà​—Ìwé pẹlẹbẹ yìí ní àwọn àwòrán ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn

      • Insight on the Scriptures (Gẹ̀ẹ́sì)​—Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ yìí ní ìdìpọ̀ méjì, ó sì ṣe àlàyé nípa àwọn èèyàn, ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀

      • “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial” (Gẹ̀ẹ́sì)​—Ìwé yìí sọ nípa ìgbà tí wọ́n kọ àwọn ìwé inú Bíbélì, ibi tí wọ́n ti kọ ọ́ àti ìdí tí wọ́n fi kọ ọ́, ó sì ṣe àlàyé ṣókí nípa ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan

      • The Bible​—God’s Word or Man’s? (Gẹ̀ẹ́sì)​—Ìwé kékeré yìí ní àwọn ìwádìí tá a fẹ̀sọ̀ ṣe nípa àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì

      • Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?​—Ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 yìí ṣe àkópọ̀ ṣókí nípa ohun tó wà nínú Bíbélì

  • Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Tún Ayé Mi Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
    • Ọkọ àtìyàwó kan jọ ń ṣiṣẹ́ nílé ìdáná

      KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | BÓ O ṢE LÈ RÍ Ẹ̀KỌ́ KỌ́ LÁTINÚ KÍKA BÍBÉLÌ

      Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Tún Ayé Mi Ṣe?

      Bíbélì kì í ṣe ìwé kan lásán. Àwọn ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa ló wà nínú rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè nípa tó lágbára lórí ìgbésí ayé rẹ. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Hébérù 4:12) Ó lágbára láti tún ìgbé ayé wa ṣe láwọn ọ̀nà méjì yìí: Ó ń tọ́ wa sọ́nà nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ báyìí, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀.​—1 Tímótì 4:8; Jákọ́bù 4:8.

      Bí ayé rẹ ṣe lè dára báyìí. Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé rẹ. Ó fúnni láwọn ìmọ̀ràn tó wúlò lórí àwọn nǹkan yìí.

      • Àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. ​—Éfésù 4:31, 32; 5:22, 25, 28, 33.

      • Bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti ìlera wa. ​—Sáàmù 37:8; Òwe 17:22.

      • Ìwà rere.​—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

      • Ọ̀rọ̀ ìnáwó.​—Òwe 10:4; 28:19; Éfésù 4:28.a

      Tọkọtaya kan nílẹ̀ Éṣíà mọyì àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì gan-an. Nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, kò tètè rọrùn fún wọn láti mọwọ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn. Àmọ́ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì sílò. Kí ló wá yọrí sí? Vicent tó jẹ́ ọkọ sọ pé: “Ohun tí mo kà nínú Bíbélì ràn mí lọ́wọ́ láti máa fi ìfẹ́ bá ìyàwó mi lò, èyí sì mú ká borí àwọn ìṣòro wa. Bá a ṣe ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò ti jẹ́ ká túbọ̀ ṣera wa lọ́kan, a sì ń láyọ̀.” Ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Annalou, fara mọ́ ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ, ó ní: “Bá a ṣe ń ka àwọn àpẹẹrẹ látinú Bíbélì ti ràn wá lọ́wọ́. Ní báyìí, mò ń láyọ̀ mo sì ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ọkọ mi, a sì ń sapá láti lé àwọn àfojúsùn wa bá.”

      Wàá mọ Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí ohun tí Vicent sọ nípa ìgbéyàwó rẹ̀, ó tún sọ pé: “Bí mo ṣe ń ka Bíbélì ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.” Àkíyèsí Vicent dá lórí ohun pàtàkì kan, ìyẹn ni pé Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run dáadáa. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní nínú àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀, wàá sì tún di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Èyí máa jẹ́ kó o rí i pé Ọlọ́run ti sọ àwọn nǹkan rere tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú fún wa, nígbà tí wàá gbádùn “ìyè tòótọ́” títí láé fáàbàdà. (1 Tímótì 6:19) Kò sí ìwé míì tó lè sọ irú ìlérí bẹ́ẹ̀ fún wa.

      Tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì, tí o kò sì dáwọ́ dúró, ìwọ́ náà á nírú àǹfààní yìí, ìyẹn ni pé ìgbésí ayé rẹ á dára báyìí, wàá sì tún sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, bó o ṣe ń ka Bíbélì, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ ìbéèrè máa wá sí ẹ lọ́kàn. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí ìtàn òṣìṣẹ́ ọba kan ní Etiópíà tó gbáyé ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀ nípa Bíbélì. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó lóye ohun tó ń kà, ó dáhùn pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?”b Kíá ló gbà kí Fílípì ran òun lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni Fílípì, ó mọ Bíbélì dáadáa, ó sì tún máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ìṣe 8:30, 31, 34) Bíi ti ọkùnrin yẹn, tí ìwọ náà bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Bíbélì, a rọ̀ ẹ́ pé kó o béèrè látorí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ẹ nínú èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí. O tún lè bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ. A rọ̀ ẹ́ pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lónìí, kó o sì jẹ́ kó darí rẹ sí ìgbésí ayé tó dára jù lọ.

      Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o kò lè fọkàn tán ohun tí Bíbélì sọ, a rọ̀ ẹ́ pé kó o wo fídíò kékeré kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì? O lè rí i tó o bá lo àmì ìlujá yìí, tàbí kó o lọ sí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo

      a Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i nípa àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tó wà nínú Bíbélì, lọ sí ìkànnì wa, jw.org/yo. Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.

      b O tún lè wo àpilẹ̀kọ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́