Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
APÁ 1 KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O PA DÀ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ?
Àwọn èèyàn Jèhófà láyé àtijọ́ ní àwọn ìṣòrò bíi tiwa, àmọ́ Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó sì ṣèlérí pé òun máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yòówù ká ní. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà, ó sì ń kíyè sí àwọn tó wà nínú agbo rẹ̀. Torí náà, ó máa ń wá àwọn àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù, ó sì ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ òun.
Apá 1 “Èyí Tí Ó Sọnù Ni Èmi Yóò Wá”
APÁ 2-4 KÍ LÓ LÈ MÚ KÓ ṢÒRO LÁTI PA DÀ?
Àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sin Jèhófà pàápàá ní àwọn ìṣòro tó mú kí wọ́n dẹwọ́ nínú ìjọsìn wọn. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan máa ń tojú sú wọn, wọ́n máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tàbí kí wọn máa dá ara wọn lẹ́bi nítorí àṣìṣe tí wọ́n ṣe sẹ́yìn. Apá yìí máa jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n fi pa dà sáàárín àwọn èèyàn rẹ̀, tí wọ́n sì ń fayọ̀ jọ́sìn Jèhófà nìṣó.
Apá 2 Àníyàn Ìgbésí Ayé—“A Há Wa Gádígádí ní Gbogbo Ọ̀nà”
Apá 3 Ẹ̀dùn Ọkàn—Bí Ẹnì Kan Bá Ṣẹ̀ Wá
Apá 4 Ẹ̀bi Ẹ̀ṣẹ̀—‘Wẹ̀ Mí Mọ́ Kúrò Nínú Ẹ̀ṣẹ̀ Mi’
APÁ 5 BÓ O ṢE LÈ PA DÀ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ
Nínú apá yìí, wàá rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà fẹ́ kó o pa dà sọ́dọ̀ òun. Wàá mọ ohun táwọn Kristẹni kan ṣe kí wọ́n lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, bí àwọn ará ni ìjọ ṣe gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀ àti bí àwọn alàgbà ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fìtara jọ́sìn Jèhófà nìṣó.