-
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?Ilé Ìṣọ́—2014 | January 1
-
-
Ṣadé: Ó kà pé: “Wàyí o, ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run sọ pé ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?’ Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún ejò pé: ‘Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti sọ nípa èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.” Látàrí èyí, ejò náà sọ fún obìnrin náà pé: ‘Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ bá jẹ nínú rẹ̀ ni ojú yín máa là, ó sì dájú pé ẹ máa dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.’”
-
-
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?Ilé Ìṣọ́—2014 | January 1
-
-
Bọ́lá: Ẹ ṣeun. Nínú ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ tẹ̀lé e, ẹ̀sùn ńlá ló fi kan Ọlọ́run. Ẹ gbọ́ nǹkan tó sọ, ó ní: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” Lọ́rọ̀ kan, ohun tí Sátánì ń sọ ni pé, irọ́ ni Ọlọ́run pa!
Ṣadé: Ẹ̀n ẹ́n, mi ò gbọ́ apá ibẹ̀ yẹn rí nínú ìtàn yìí.
Bọ́lá: Nígbà tí Sátánì pe Ọlọ́run ní òpùrọ́, ọ̀ràn ńlá ló dá sílẹ̀. Ọ̀ràn náà sì máa gba àkókò láti yanjú. Ǹjẹ́ ẹ mọ ìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀?
Ṣadé: Rárá, kò tíì yé mi dáadáa.
Bọ́lá: Ó dáa, ẹ jẹ́ kí n fún yín ní àpèjúwe kan. Ká sọ pé lọ́jọ́ kan mo wá bá yín, mo sì sọ fún yín pé mo lágbára jù yín lọ. Báwo ni ẹ ṣe máa fi hàn mí pé ohun tí mo sọ ò rí bẹ́ẹ̀?
Ṣadé: Àfi kí àwa méjèèjì ṣe ìdánrawò, ìyẹn la máa fi mọ ẹni tó lágbára jù.
Bọ́lá: Bó ṣe rí gan ni ẹ sọ. Ńṣe ni a máa wá nǹkan tó wúwo, àá wá wo ẹni tó lè dáa gbé nínú àwa méjèèjì. Ìyẹn rọrùn láti yanjú, àbí?
Ṣadé: Ọ̀rọ̀ yín ti ń yé mi.
Bọ́lá: Àmọ́, ká ní ohun tí mo sọ ni pé mo máa ń ṣòótọ́ jù yín lọ. Ǹjẹ́ ìyẹn ò lè ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?
Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ ńlá ni.
Bọ́lá: Ó ṣe tán, agbára kọ́ la máa fi mọ̀ pé ẹnì kan ṣòótọ́.
Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni.
Bọ́lá: Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn le gbà yanjú ọ̀ràn yìí ni pe ká fi àkókò tó pọ̀ sílẹ̀, kí àwọn èèyàn lè kíyè sí àwa méjèèjì, kí wọ́n lè mọ ẹni tó ń ṣòótọ́ jù nínú wa. Àbí?
Ṣadé: Bẹ́ẹ̀ ni.
Bọ́lá: Ó dáa, ẹ tún ìwé Jẹ́nẹ́sísì tá a kà lẹ́ẹ̀kan yẹ̀ wò. Ṣé ohun tí Sátánì sọ ni pé òun lágbára ju Ọlọ́run lọ?
Ṣadé: Rárá o.
Bọ́lá: Ká ní ó sọ bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé Ọlọ́run ò ní gba àkókò tí á fi yanjú rẹ̀. Àmọ́, ohun tí Sátánì sọ ni pé òun ń ṣòótọ́ ju Ọlọ́run lọ. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ fún Éfà ni pé ‘irọ́ ni Ọlọ́run ń pa fún un yín, ṣùgbọ́n òótọ́ lèmi ń sọ.’
Ṣadé: Ó ga o.
Bọ́lá: Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó mọ̀ pé ọ̀nà tó dáa jù láti yanjú ọ̀ràn náà ni pé kí òun fi ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀. Tó bá yá, òótọ́ ọ̀rọ̀ á fara hàn, àá sì mọ ẹni tó ń sòótọ́ àti ẹni tó ń pa irọ́.
-