-
Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi WàIlé Ìṣọ́—2007 | September 15
-
-
Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa. Ó ní Sátánì Èṣù gbẹnu ejò kan bá Éfà sọ̀rọ̀ pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Ni Éfà bá sọ àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un. Sátánì wá sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ yìí mú kí igi náà dà bí èyí tó fani mọ́ra gan-an lójú Éfà débi pé ó “mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Bí Ádámù àti Éfà ṣe ṣi òmìnira tí wọ́n ní láti yan ohun tó wù wọ́n lò nìyẹn, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ o mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe burú tó? Ṣe ni Èṣù ta ko Ọlọ́run pé irọ́ lohun tó sọ fún Ádámù. Ó dọ́gbọ́n sọ pé kò pọn dandan kí Jèhófà máa tọ́ Ádámù àti Éfà sọ́nà kí wọ́n tó lè mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Nítorí náà, ńṣe ni Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ẹ̀dá èèyàn, àti pé kò bófin mu pé kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ ni bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ tàbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, èyí ló sì jẹ́ ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kí ni Ọlọ́run tòótọ́ ṣe láti yanjú ọ̀ràn pàtàkì yìí?
-
-
Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi WàIlé Ìṣọ́—2007 | September 15
-
-
Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún báyìí tí Sátánì ti fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso. Kí wá làwọn nǹkan tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà náà fi hàn? Ó dáa, ẹ jẹ́ ká gbé kókó méjì yẹ̀ wò nínú ẹ̀sùn tí Sátánì fi kan Ọlọ́run. Àkọ́kọ́, Sátánì fi dá Éfà lójú pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4) Bí Sátánì ṣe sọ pé Ádámù àti Éfà ò ní kú tí wọ́n bá jẹ èso tí Jèhófà sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ, ohun tó ń sọ ni pé òpùrọ́ ni Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ẹ̀sùn ńlá nìyẹn! Àbí, tó bá jẹ́ pé irọ́ ni Ọlọ́run pa lóòótọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run máa tún ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé mọ́? Àmọ́, kí làwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní àkókò tó ti kọjá fi hàn?
Ádámù àti Éfà dẹni tó ń ṣàìsàn, wọ́n ń ní ìrora, wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ọjọ́ Ádámù tí ó fi wà láàyè jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n, ó sì kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; 5:5) Ikú tó jẹ́ nǹkan ìbànújẹ́ yìí sì lohun tí gbogbo ẹ̀dá èèyàn jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ti wá fi hàn pé Sátánì jẹ́ ‘òpùrọ́ àti baba irọ́,’ ó sì fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́.”—Jòhánù 8:44; Sáàmù 31:5.
-