-
Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi WàIlé Ìṣọ́—2007 | September 15
-
-
Bíbélì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa. Ó ní Sátánì Èṣù gbẹnu ejò kan bá Éfà sọ̀rọ̀ pé: “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?” Ni Éfà bá sọ àṣẹ tí Ọlọ́run pa fún un. Sátánì wá sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Ọ̀rọ̀ tí Sátánì sọ yìí mú kí igi náà dà bí èyí tó fani mọ́ra gan-an lójú Éfà débi pé ó “mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́.” Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Bí Ádámù àti Éfà ṣe ṣi òmìnira tí wọ́n ní láti yan ohun tó wù wọ́n lò nìyẹn, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀ nípa ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ o mọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe burú tó? Ṣe ni Èṣù ta ko Ọlọ́run pé irọ́ lohun tó sọ fún Ádámù. Ó dọ́gbọ́n sọ pé kò pọn dandan kí Jèhófà máa tọ́ Ádámù àti Éfà sọ́nà kí wọ́n tó lè mọ ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Nítorí náà, ńṣe ni Sátánì fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso ẹ̀dá èèyàn, àti pé kò bófin mu pé kó máa ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ọ̀ràn tí Sátánì dá sílẹ̀ ni bóyá Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ tàbí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, èyí ló sì jẹ́ ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kí ni Ọlọ́run tòótọ́ ṣe láti yanjú ọ̀ràn pàtàkì yìí?
-
-
Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi WàIlé Ìṣọ́—2007 | September 15
-
-
Sátánì tún sọ fún Éfà pé: “Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú [èso igi tóun kà léèwọ̀] ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin [Ádámù àti Éfà] yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:5) Ńṣe ni Sátánì lo ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí láti fi mú káwọn èèyàn rò pé èèyàn lè kúrò lábẹ́ Ọlọ́run kó wá máa ṣàkóso ara rẹ̀. Ó tún fi ọ̀rọ̀ yìí kan náà mú kí wọ́n máa rò pé nǹkan á túbọ̀ dáa fún aráyé tí wọ́n ò bá sí lábẹ́ àkóso Ọlọ́run. Ṣó ti wá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?
Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn tí Sátánì ti sọ̀rọ̀ yẹn, onírúurú orílẹ̀-èdè ti ṣàkóso ayé, wọ́n sì ti kúrò lójú ọpọ́n gẹ́gẹ́ bí agbára ayé. Àwọn èèyàn ti gbìyànjú onírúurú ètò ìjọba tí wọ́n hùmọ̀. Àmọ́ àjẹkún ìyà laráyé ń jẹ. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì wo sàkun gbogbo rẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, ó ní: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Wòlíì Jeremáyà pẹ̀lú kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àní àwọn ohun tí wọ́n ti gbé ṣe lágbo ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ láwọn ọdún àìpẹ́ yìí pàápàá ò lè já òótọ́ ọ̀rọ̀ táwọn òǹkọ̀wé Bíbélì yìí sọ ní koro. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ Bíbélì yìí.
-