-
Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí ÈṣùIlé-Ìṣọ́nà—1994 | April 1
-
-
6. Báwo ni Satani ṣe pe ìwàrere-ìṣeun àti ipò ọba aláṣẹ Jehofa níjà?
6 Ṣùgbọ́n Satani sọ púpọ̀ síi. Ó ń báa nìṣó pé: “Nítorí Ọlọrun mọ̀ pé, ní ọjọ́ tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, nígbà náà ni ojú yín yóò là, ẹ̀yin óò sì dàbí Ọlọrun, ẹ óò mọ rere àti búburú.” Bí Satani ti wí, Jehofa Ọlọrun—tí o ti pèsè jaburata fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́—fẹ́ láti dù wọ́n ní ohun àgbàyanu kan. Ó ń fẹ́ láti ṣèdíwọ́ fún wọn láti máṣe dàbí àwọn ọlọrun. Nípa báyìí, Satani pe ìwàrere-ìṣeun Ọlọrun níjà. Ó tún gbé ìtẹ́ra-ẹni lọ́rùn àti ìmọ̀ọ́mọ̀ gbójúfo àwọn òfin Ọlọrun lékè, ní sísọ pé híhùwà ní ọ̀nà yìí yóò ṣàǹfààní. Nídìí èyí, Satani pe ipò ọba aláṣẹ Ọlọrun lórí àwọn ìṣẹ̀dá Rẹ̀ níjà, ní fífẹ̀sùnkàn pé Ọlọrun kò ní ẹ̀tọ́ láti fi ààlà sórí ohun tí ènìyàn bá ṣe.
7. Nígbà wo ni a kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, báwo ni wọn sì ṣe farajọra lónìí?
7 Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Satani wọ̀nyẹn, a bẹ̀rẹ̀ síí gbọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Àwọn ẹ̀kọ́ búburú wọ̀nyí ṣì ń gbé irú àwọn ìlànà tí ó farajọ ọ́ tí kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun lékè. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe nínú ọgbà Edeni, Satani, tí àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹ̀mí ti darapọ̀ mọ́, ṣì ń gbé ìpèníjà dìde sí ẹ̀tọ̀ Ọlọrun láti fi ọ̀pá ìdíwọ̀n lélẹ̀ fún ọ̀nà ìgbàgbégbèésẹ̀. Ó ṣì ń ṣiyèméjì nípa ipò ọba aláṣẹ Jehofa tí ó sì ń gbìyànjú láti darí àwọn ènìyàn láti ṣàìgbọràn sí Baba wọn ọ̀run.—1 Johannu 3:8, 10.
-
-
Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí ÈṣùIlé-Ìṣọ́nà—1994 | April 1
-
-
13. Irọ́ wo ni Satani ti pa fún aráyé láti ìgbà ti Edeni?
13 Lójú Efa, Satani fẹ̀sùn irọ́ pípa kan Jehofa tí ó sì sọ pé ẹ̀dá ènìyàn lè dàbí ọlọrun bí wọ́n bá ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá wọn. Ipò ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lónìí ti fẹ̀ríhàn pé Satani ni òpùrọ́, kìí ṣe Jehofa. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn lónìí kìí ṣe ọlọrun! Bí ó ti wù kí ó rí, Satani fi irọ́ mìíràn gbe ti àkọ́kọ́ lẹ́sẹ̀. Ó gbé èrò náà kalẹ̀ pé ọkàn ènìyàn jẹ́ àìlèkú, tí kìí tipa báyìí kú. Ó fi ṣíṣeéṣe náà láti dàbí ọlọrun lọ aráyé lọ́nà mìíràn. Nígbà náà, lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ èké yẹn, ó gbé àwọn ẹ̀kọ́ iná ọ̀run àpáàdì, pọ́gátórì, ìbẹ́mìílò, àti ìjọ́sìn àwọn babańlá lékè. Àwọn irọ́ wọ̀nyí ṣì mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún nígbèkùn.—Deuteronomi 18:9-13.
-
-
Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ní Ìdojú Ìjà Kọ Ẹ̀kọ́ Àwọn Ẹ̀mí ÈṣùIlé-Ìṣọ́nà—1994 | April 1
-
-
16. Kí ni àwọn àbájáde onígbà gígùn tí ó máa ń wà nígbà tí àwọn ènìyàn bá tẹ̀lé ọgbọ́n ti araawọn?
16 Nípasẹ̀ irọ́ yìí nínú ọgbà Edeni, Satani fún Adamu àti Efa níṣìírí láti lépa òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun kí wọ́n sì gbáralé ọgbọ́n tiwọn fúnraawọn. Lónìí, a rí àbájáde onígbà gígùn tí ìyẹn ní nínú ìwà ipá, ìnira ètò ọrọ̀-ajé, ogun, àti àìbáradọ́gba híhàn gbangba tí ó wà nínú ayé lónìí. Abájọ tí Bibeli fi sọ pé: “Ọgbọ́n ayé yìí wèrè ni lọ́dọ̀ Ọlọrun”! (1 Korinti 3:19) Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn fi ìwà òmùgọ̀ yàn láti jìyà ju kí wọ́n fiyèsí àwọn ẹ̀kọ́ Jehofa. (Orin Dafidi 14:1-3; 107:17) Àwọn Kristian, tí wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, yẹra fún kíkó sínú pàkúté yẹn.
-