-
“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”Ilé Ìṣọ́—2013 | January 1
-
-
Tó bá rò bẹ́ẹ̀, àṣìṣe ńlá ló ṣe o. Àgàgà tó bá jẹ́ pé irú èrò yìí ni wọ́n gbìn sí Kéènì lọ́kàn bó ṣe ń dàgbà, kò sí bí ìyẹn kò ṣe ní sọ ọ́ di ẹni tó jọ ara rẹ̀ lójú. Nígbà tí Éfà bí ọmọkùnrin kejì, wọn kò sọ irú ọ̀rọ̀ ìwúrí bẹ́ẹ̀ nípa ìyẹn. Wọ́n sọ ọ́ ní Ébẹ́lì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Èémí Àmíjáde,” tàbí “Asán.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:2) Àbí wọ́n ti rò pé Ébẹ́lì kò ní fi bẹ́ẹ̀ rọ́wọ́ mú ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní orúkọ yẹn, bíi pé wọ́n kò gbójú lé e tó Kéènì? A ò kúkú lè sọ.
-
-
“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”Ilé Ìṣọ́—2013 | January 1
-
-
Ó dájú pé bí àwọn ọmọkùnrin méjèèjì ṣe ń dàgbà, Ádámù kọ́ wọn ní iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n á fi máa ṣètìlẹyìn fún ìdílé náà. Kéènì di àgbẹ̀, Ébẹ́lì sì ń da àgùntàn.
-
-
“Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Ó Kú, Ó Ń Sọ̀rọ̀ Síbẹ̀”Ilé Ìṣọ́—2013 | January 1
-
-
Ó dájú pé Ébẹ́lì máa ń fara balẹ̀ ronú nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Fojú inú yàwòrán rẹ̀ bí ó ṣe ń tọ́jú agbo ẹran rẹ̀. Àwọn darandaran sábà máa ń rìn káàkiri gan-an. Torí náà, yóò máa da àwọn ẹran ọ̀sìn náà lọ sí orí àwọn òkè àti àfonífojì, yóò kó wọn sọdá odò, yóò dà wọ́n lọ sí ibikíbi tí wọ́n bá ti lè rí koríko tútù yọ̀yọ̀ jẹ, ibi tí wọ́n bá ti lè rí omi mu àti ibi ààbò tí wọ́n ti lè sinmi. Nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń dáàbò bo ara wọn rárá, ti àwọn àgùntàn yọyẹ́. Àfi bíi pé ṣe ni Ọlọ́run dìídì dá wọn lọ́nà tó fi jẹ́ pé èèyàn ní láti máa tọ́ wọn sọ́nà, kó sì máa dáàbò bò wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí Ébẹ́lì wá rí i pé òun náà nílò ìtọ́sọ́nà àti ààbò àti ìtọ́jú Ọlọ́run tó ní ọgbọ́n àti agbára ju ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí. Ó dájú pé ọ̀pọ̀ irú èrò bẹ́ẹ̀ ni yóò máa bá Ọlọ́run sọ nígbà tó bá ń gbàdúrà, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ máa pọ̀ sí i.
Àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá tí Ébẹ́lì ń rí mú kó gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ onífẹ̀ẹ́
-