ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | June 15
    • Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé a dá àwọn òbí wọn ní pípé àti pé ète Jèhófà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni pé kí ẹ̀dá ènìyàn wà láàyè títí láé. Ó ṣeé ṣe pé Ádámù àti Éfà ṣàpèjúwe ọgbà ẹlẹ́wà Édẹ́nì fún wọn, wọ́n sì ti ní láti ṣàlàyé bákan ṣáá, ìdí tí a fi lé wọn jáde kúrò nínú ilé párádísè kan bẹ́ẹ̀. Kéènì àti Ébẹ́lì pẹ̀lú ti lè mọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ àtọ̀runwá tí a kọ sílẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ ète rẹ̀ jáde láti mú ọ̀ràn tọ́ ní àkókò yíyẹ fún àǹfààní àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i.

      Kíkọ́ nípa Jèhófà àti àwọn ànímọ́ rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ mú kí Kéènì àti Ébẹ́lì ní ìfẹ́ ọkàn fún ojú rere Ọlọ́run. Nítorí náà, wọ́n tọ Jèhófà lọ nípa rírúbọ sí i. Ìròyìn Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣe, ní òpin ọjọ́ wọnnì tí Kéènì mu ọrẹ nínú èso ilẹ̀ fún OLÚWA wá. Àti Ébẹ́lì, òun pẹ̀lú mú nínú àkọ́bí ẹran ọ̀sìn àní nínú àwọn tí ó sanra.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4.

  • Kí Ni Ó Túmọ̀ Sí Láti Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1996 | June 15
    • Èé ṣe tí Jèhófà fi kọ ẹbọ Kéènì? Ohun kan ha ṣàìtọ́ pẹ̀lú ìjójúlówó ọrẹ rẹ̀ bí? Inú ha bí Jèhófà nítorí pé Kéènì fi “èso ilẹ̀” rúbọ dípò ẹbọ ẹran bí? Ó lè ṣàìjẹ́ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ọlọ́run fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba ọrẹ ọkà àti àwọn èso ilẹ̀ míràn láti ọwọ́ ọ̀pọ̀ olùjọsìn rẹ̀. (Léfítíkù 2:1-16) Dájúdájú, nígbà náà, ohun kan ṣàìtọ́ nínú ọkàn-àya Kéènì. Jèhófà lè mọ ọkàn-àya Kéènì, ó sì kìlọ̀ fún un pé: “Èé ṣe tí inú fi ń bí ọ? èé sì ti ṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ́ bá ṣe rere, ara kì yóò ha yá ọ? Bí ìwọ kò bá sì ṣe rere, ẹ̀ṣẹ́ ba ní ẹnu ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí.”—Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́