-
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
-
-
‘A ṢÍ I NÍPÒ PA DÀ LÁTI MÁ ṢE RÍ IKÚ’
Báwo ni Énọ́kù ṣe kú? Ohun kan ni pé ikú rẹ̀ ṣeni ní kàyéfì ju ìgbésí ayé rẹ̀ lọ. Apá kan nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé: “Énọ́kù sì ń bá a nìṣó ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́. Lẹ́yìn náà, òun kò sì sí mọ́, nítorí tí Ọlọ́run mú un lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:24) Lọ́nà wo ni Ọlọ́run gbà mú Énọ́kù lọ? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé, ó ní: “Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú, a kò sì rí i níbi kankan nítorí tí Ọlọ́run ti ṣí i nípò padà; nítorí ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀, ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” (Hébérù 11:5) Kí ní Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “a ṣí Énọ́kù nípò padà láti má ṣe rí ikú”? Àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan sọ pé Ọlọ́run mú Énọ́kù lọ sí ọ̀run. Àmọ́ ìyẹn kò lè jóòótọ́. Torí Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù Kristi ni ẹni àkọ́kọ́ tí Ọlọ́run jí dìde sí ọ̀run.—Jòhánù 3:13.
Ó dáa, báwo ni Ọlọ́run ṣe ṣí Énọ́kù nípò pa dà tó fi jẹ́ pé kò rí ikú”? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà rọra mú kí Énọ́kù sùn kó sì gba ibẹ̀ kú láìjẹ ìrọra kankan. Àmọ́ kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó yé e pé, ‘ó ti wu òun dáadáa.’ Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ṣáájú kí Énọ́kù tó kú, Ọlọ́run jẹ́ kó rí bí ayé ṣe máa rí lẹ́yìn tó bá di Párádísè. Énọ́kù sùn nínú oorun ikú lẹ́yìn tó rí ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà tẹ́wọ́ gba òun. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nípa Énọ́kù àtàwọn olóòótọ́ míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ó sọ pé: “Gbogbo àwọn wọ̀nyí kú nínú ìgbàgbọ́.” (Hébérù 11:13) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn èèyàn burúkú yẹn wá òkú Énọ́kù, àmọ́ wọn ‘kò rí i níbi kankan.’ Jèhófà kò jẹ́ káwọn èèyànkéèyàn náà rí òkú Énọ́kù kí wọ́n má bàa fi òkú rẹ̀ gbé ìjọsìn èké lárugẹ.b
Bá a ṣe ń ronú lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, ẹ jẹ́ ká fọkàn yàwòrán ọ̀nà tó ṣeé ṣe kí Énọ́kù gbà kú. Èyí kàn jẹ́ ọ̀kan nínú ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀. Fojú inú wo bí Énọ́kù ṣe ń sá lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́ tẹnu-tẹnu. Àwọn èèyàn burúkú ń lé e bọ̀, inú ń bí wọn gidigidi nítorí ìdájọ́ tí Énọ́kù kéde fún wọn. Énọ́kù wá ríbi kan sá pa mọ́ sí, síbẹ̀ ó mọ̀ pé bópẹ́ bóyá ọwọ́ á tẹ òun. Ó ń ronú nípa bí àwọn èèyàn burúkú yẹn ṣe máa pa òun nípakúpa. Bó ṣe ń sinmi, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, Ọlọ́run sì jẹ́ kó ní ìtura ọkàn. Ọlọ́run wá fi ìran kan hàn án, ó sì dà bíi pé ńṣe ni Énọ́kù wà nínú ìran yẹn gan-an.
Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn fẹ́ pa Énọ́kù nípakúpa kí Jèhófà tó mú un lọ
Ó ṣeé ṣe kó rí ilẹ̀ ayé tó yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó wà. Gbogbo ibẹ̀ rẹwà bí ọgbà Édẹ́nì, àmọ́ kò sáwọn Kérúbù tó ń ṣọ́ ẹnubodè. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣeré kiri, wọ́n sì ní ìlera tó dára. Àlàáfíà tó wà níbẹ̀ kọjá àfẹnusọ. Kò sẹ́ni tó kórìíra ọmọnìkejì tàbí ṣe ẹ̀tanú síra wọn. Èyí yàtọ̀ sí ayé tí Énọ́kù ń gbé. Ọkàn Énọ́kù balẹ̀ torí ó rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ òun. Ó sì dá a lójú pé inú ayé tó rí rèǹtèrente yìí lòun máa gbé. Jèhófà jẹ́ kó ní ìtura ọkàn, ló bá rọra forí lélẹ̀, ó sì sùn nínú oorun ikú láìjẹ ìrora.
Énọ́kù ṣì ń sùn nínú oorun ikú títí dòní, síbẹ̀ Ọlọ́run kò gbàgbé rẹ̀ torí pé agbára ìrántí Ọlọ́run kò láàlà. Jésù tiẹ̀ ṣèlérí pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí Ọlọ́run máa gbọ́ ohùn Kristi, wọ́n á jí dìde látinú sàréè, wọ́n á sì bọ́ sínú ayé tuntun tó rẹwà, tí àlàáfíà á wà níbẹ̀ títí láé.—Jòhánù 5:28, 29.
-
-
“Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017 | No. 1
-
-
b Lọ́nà kan náà, Ọlọ́run ò jẹ́ kọ́wọ́ àwọn èèyàn tẹ òkú Mósè àti ti Jésù, kí wọ́n má báa fi gbé ìsìn èké lárugẹ.—Diutarónómì 34:5, 6; Lúùkù 24:3-6; Júúdà 9.
-