ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀mí
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • 5. Má ṣe ohun tó máa pa ọmọ inú oyún lára

      Obìnrin kan tó lóyún ń fọwọ́ pa ikùn ẹ̀.

      Dáfídì sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń kíyè sí gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọmọ tó ṣì wà nínú oyún. Ka Sáàmù 139:13-17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

      • Lójú Jèhófà, ṣé látìgbà tí wọ́n ti lóyún ọmọ kan ni ìwàláàyè ẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni àbí ìgbà tí wọ́n bá bí i?

      Nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà ṣe àwọn òfin kan láti dáàbò bo àwọn aboyún àtàwọn ọmọ inú wọn. Ka Ẹ́kísódù 21:22, 23, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Tí ẹnì kan bá ṣèèṣì pa ọmọ inú oyún, kí ni Jèhófà ní kí wọ́n ṣe fún ẹni náà?

      • Tó bá wá jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ inú oyún, báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Jèhófà?b

      • Kí lèrò ẹ nípa ọwọ́ tí Ọlọ́run fi mú ọ̀rọ̀ yìí?

      Wo FÍDÍÒ yìí.

      FÍDÍÒ: Fi Hàn Pé Ẹ̀mí Èèyàn Jọ Ẹ́ Lójú (5:00)

      Nígbà míì, tí obìnrin kan tó lóyún bá tiẹ̀ mọyì ẹ̀mí, ó lè láwọn ìṣòro kan táá mú kó gbà pé àfi kóun ṣẹ́ oyún náà. Ka Àìsáyà 41:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

      • Tí obìnrin kan bá láwọn ìṣòro kan nínú oyún, táwọn kan sì sọ pé ohun tó máa dáa jù ni pé kó ṣẹ́ oyún náà, ọ̀dọ̀ ta ló yẹ kó wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

  • Fi Hàn Pé O Mọyì Ẹ̀mí
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
    • b Tí ẹnì kan tó ti ṣẹ́yún rí bá ronú pìwà dà, kò yẹ kó máa banú jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ torí pé Jèhófà máa dárí jì í. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, ka àpilẹ̀kọ tó wà ní apá Ṣèwádíì nínú ẹ̀kọ́ yìí, tí àkòrì ẹ̀ sọ pé “Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìṣẹ́yún?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́