ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2004 | March 15
    • Mósè ń lọ sí Íjíbítì pẹ̀lú Sípórà, aya rẹ̀, àtàwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì, Élíésérì àti Gẹ́ṣómù, nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí wáyé: “Ó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà ní ibùwọ̀ pé Jèhófà pàdé rẹ̀, ó sì ń wá ọ̀nà láti fi ikú pa á. Níkẹyìn, Sípórà mú akọ òkúta, ó sì dá adọ̀dọ́ ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì mú kí ó kan ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì wí pé: ‘Nítorí pé ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀ ni o jẹ́ fún mi.’ Nítorí náà, ó jẹ́ kí ó lọ. Ní àkókò yẹn, obìnrin náà wí pé: ‘Ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀,’ nítorí ìdádọ̀dọ́.” (Ẹ́kísódù 4:20, 24-26) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àyọkà Bíbélì yìí kò ṣe kedere, bẹ́ẹ̀ ni kò sì rọrùn láti sọ ohun tó túmọ̀ sí ní pàtó, Ìwé Mímọ́ tànmọ́lẹ̀ díẹ̀ sí àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́—2004 | March 15
    • Nígbà tí Sípórà gbìyànjú láti ṣe àtúnṣe ọ̀ràn náà, ẹsẹ̀ ta ni ó jẹ́ kí awọ adọ̀dọ́ ọmọ rẹ̀ kàn nígbà tó dá a tán? Áńgẹ́lì Jèhófà ló ní agbára láti pa ọmọ tí wọn kò dá adọ̀dọ́ fún náà. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu pé Sípórà ti gbọ́dọ̀ jẹ́ kí awọ adọ̀dọ́ ọmọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ áńgẹ́lì náà, kí ìyẹn lè jẹ́ ẹ̀rí pé Sípórà fara mọ́ májẹ̀mú náà.

      Ọ̀rọ̀ tí Sípórà sọ pé, “ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀ ni o jẹ́ fún mi” jẹ́ ohun tó ṣàjèjì. Kí ni gbólóhùn yìí fi hàn nípa Sípórà? Nípa fífaramọ́ ohun tí májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́ sọ, Sípórà gbà pé òun wà nínú májẹ̀mú kan pẹ̀lú Jèhófà. Májẹ̀mú Òfin tí Jèhófà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fi hàn pé nínú májẹ̀mú kan, a lè ka Jèhófà sí ọkọ kí á sì ka ẹlòmíràn tó tún wà nínú májẹ̀mú náà sí ìyàwó. (Jeremáyà 31:32) Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tí Sípórà ń pe Jèhófà ní “ọkọ ìyàwó ẹ̀jẹ̀” (nípasẹ̀ áńgẹ́lì náà), ó jọ pé ńṣe ni Sípórà ń fi hàn bí òun ṣe fara mọ́ ohun tí májẹ̀mú náà sọ. Ńṣe ló dà bíi pé ó tẹ́wọ́ gba ipò aya nínú májẹ̀mú ìdádọ̀dọ́, ó sì ka Jèhófà Ọlọ́run sí ọkọ. Èyí ó wù kó jẹ́, nítorí pé ó ṣègbọràn láìjáfara sí ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ẹ̀mí ọmọ rẹ̀ kò sí nínú ewu mọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́