-
Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà GbogboIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019 | February
-
-
3. (a) Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́? (b) Àpẹẹrẹ wo ló jẹ́ ká mọ ohun tí ìwà títọ́ túmọ̀ sí?
3 Ká tó lè sọ pé ẹnì kan jẹ́ oníwà títọ́, ó gbọ́dọ̀ máa hàn nínú ìwà tó ń hù lójoojúmọ́ pé ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ, pé òun ló ń fayé rẹ̀ sìn àti pé àwọn nǹkan tí Jèhófà kà sí pàtàkì lòun náà kà sí pàtàkì. Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná. Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n tú sí “ìwà títọ́” nínú Bíbélì túmọ̀ sí pé kí nǹkan pé, kí ara ẹ̀ dá ṣáṣá, kó má sì ní àbùkù. Bí àpẹẹrẹ, Òfin Mósè sọ pé táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá máa fi ẹran rúbọ sí Jèhófà, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.b (Léf. 22:21, 22) Òfin náà kò gbà wọ́n láyè láti fi ẹran tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kán, tí etí rẹ̀ re, tí ojú rẹ̀ fọ́ tàbí tó ń ṣàìsàn rúbọ. Ó ṣe pàtàkì kí ẹran tí wọ́n máa fi rúbọ sí Jèhófà dá ṣáṣá, kó má sì lábùkù, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà kò ní tẹ́wọ́ gbà á. (Mál. 1:6-9) Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ohun tí kò lábùkù ni Jèhófà fẹ́. Ká sọ pé àwa náà bá fẹ́ ra èso, ìwé tàbí ohun èlò míì, ó dájú pé a ò ní gba èyí tó níhò tàbí tí apá kan nínú rẹ̀ ti bà jẹ́. Èyí tó pé tí kò sì lábùkù la máa gbà. Lọ́nà kan náà, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá, kò sì yẹ ká máa ṣe ẹsẹ̀ kan ilé ẹsẹ̀ kan òde.
-
-
Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà GbogboIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019 | February
-
-
b Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò fún “dá ṣáṣá” nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹran jọra pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n máa ń lò fún kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́ tàbí adúróṣinṣin.
-