-
“Ẹ Máa Sá fún Àgbèr蔑Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
3. Kí lọgbọ́n tí Báláámù dá yọrí sí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
3 Ǹjẹ́ ọgbọ́n tó dá yìí ṣiṣẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣiṣẹ́ dé ìwọ̀n àyè kan. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó sínú ìdẹkùn yìí nípa níní “ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.” Wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn àwọn òrìṣà ilẹ̀ Móábù, tó fi mọ́ Báálì Péórù, òrìṣà ẹlẹ́gbin tí wọ́n sọ pó jẹ́ òrìṣà ìbímọlémọ, tàbí ti ìbálòpọ̀. Nítorí ìyẹn, ẹgbàá méjìlá [24,000] ló ṣègbé lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọ́n tó dé Ilẹ̀ Ìlérí. Àdánù ńláǹlà mà lèyí o!—Númérì 25:1-9.
-
-
“Ẹ Máa Sá fún Àgbèr蔑Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
4. Kí nìdí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣàgbèrè?
4 Kí ló fa àdánù yìí gan-an? Ìdí ni pé lílọ tí ọ̀pọ̀ lára wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà ti mú kí ọkàn wọn dìdàkudà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run yìí ló dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì, òun ló bọ́ wọn nígbà tí wọ́n wà ní aginjù, òun ló sì pa wọ́n mọ́ títí tí wọ́n fi dé bèbè Ilẹ̀ Ìlérí. (Hébérù 3:12) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣe ìwà hù, bí àwọn kan nínú wọn ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”a—1 Kọ́ríńtì 10:8.
-
-
“Ẹ Máa Sá fún Àgbèr蔑Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
a Gbogbo àwọn “olórí nínú àwọn ènìyàn náà,” tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọkùnrin [1,000], táwọn onídàájọ́ pa àtàwọn tí Jèhófà fúnra rẹ̀ pa, wà lára àwọn tí ìwé Númérì sọ pé wọ́n bá ẹ̀ṣẹ̀ náà rìn.—Númérì 25:4, 5.
-