ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Jèhófà Mọ Àwọn Tí Í Ṣe Tirẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́—2014 | July 15
    • 4. Kí ló dá Pọ́ọ̀lù lójú, báwo ló sì ṣe jẹ́ kí Tímótì mọ̀ bẹ́ẹ̀?

      4 Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Jèhófà máa mọ̀ téèyàn bá ń sìn ín lọ́nà àgàbàgebè, ó sì tún dá a lójú pé Jèhófà lè dá àwọn tó ń ṣègbọràn sí I mọ̀. Èyí ṣe kedere nínú àṣàyàn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò nígbà tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ̀wé sí Tímótì. Lẹ́yìn tó ti tọ́ka sí bí àwọn apẹ̀yìndà ṣe fẹ́ ba àjọṣe tí àwọn kan nínú ìjọ ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́, ó sọ pé: “Láìka gbogbo èyíinì sí, ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run dúró sẹpẹ́, ó ní èdìdì yìí: ‘Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀,’ àti pé: ‘Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.’”—2 Tím. 2:18, 19.

  • “Jèhófà Mọ Àwọn Tí Í Ṣe Tirẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́—2014 | July 15
    • 6 Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ohun tí Mósè sọ nínú Númérì 16:5, nípa Kórà àtàwọn tí wọ́n jọ dìtẹ̀ ló mẹ́nu kan gbólóhùn náà, “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run.” Ó dájú pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Mósè yẹn kó bàa lè fún Tímótì níṣìírí kó sì rán an létí pé Jèhófà lágbára láti mọ àwọn tó ń dáná ọ̀tẹ̀, ó sì mọ bó ṣe lè paná ọ̀tẹ̀ náà. Torí náà, bí Jèhófà kò ṣe gbà kí Kórà dí ète rẹ̀ lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, ó dájú pé kò ní gbà kí àwọn apẹ̀yìndà tó wà nínú ìjọ ṣe bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ohun tí “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run” dúró fún. Síbẹ̀, ó ṣe kedere pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù lò yẹn mú kó dá Tímótì lójú pé Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ṣeé fọkàn tán.

  • “Jèhófà Mọ Àwọn Tí Í Ṣe Tirẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́—2014 | July 15
    • 8, 9. Kí la rí kọ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “èdìdì” nínú àpèjúwe rẹ̀?

      8 Àpèjúwe tí Pọ́ọ̀lù lò nínú 2 Tímótì 2:19 fi hàn pé wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sárá ìpìlẹ̀ ilé kan, tàbí lédè mìíràn wọ́n fi èdìdì ṣe àmì sí i lára. Láyé àtijọ́, ó wọ́pọ̀ gan-an pé kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ sárá ìpìlẹ̀ ilé kan, bóyá káwọn èèyàn lè mọ bíríkìlà tó kọ́ ilé náà tàbí ẹni tó ni ín. Pọ́ọ̀lù ni òǹkọ̀wé Bíbélì àkọ́kọ́ tó lo àpèjúwe yìí.a Gbólóhùn méjì ló fara hàn nínú àmì tí wọ́n fi èdìdì ṣe sára “ìpìlẹ̀ lílágbára ti Ọlọ́run.” Àkọ́kọ́, “Jèhófà mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀” àti èkejì, “Kí gbogbo ẹni tí ń pe orúkọ Jèhófà kọ àìṣòdodo sílẹ̀ ní àkọ̀tán.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí mú ká rántí ohun tá a kà nínú Númérì 16:5.—Kà á.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́