-
Ìrìn Àjò Láti Íjíbítì Sí Ilẹ̀ ÌléríWo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà
-
-
Nígbà tí àkókò jàjà tó fún Ísírẹ́lì láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gba ọ̀nà àríwá ní tààràtà. Ọ̀nà tí wọ́n gbà mú kí wọ́n já sí ọ̀gangan ilẹ̀ Édómù wọ́n sì kọjú síhà àríwá ní ojú “ọ̀nà ọba,” ìyẹn ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní Òpópónà Ọba. (Nu 21:22; Di 2:1-8) Kò rọrùn rárá fún odindi orílẹ̀-èdè kan, tó ní àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, ẹran ọ̀sìn, àtàwọn àgọ́, láti gba ojú ọ̀nà yìí. Wọ́n ní láti rìn kọ́lọkọ̀lọ lọ sísàlẹ̀ kí wọ́n sì tún gòkè padà wá jáde lójú ọ̀nà tó ṣòro láti rìn náà, ìyẹn àwọn ọ̀nà Séréédì àti Áánónì (tó jìnnà sísàlẹ̀ tó okòó lé lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta mítà [520 m]).—Di 2:13, 14, 24.
-