ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb13 ojú ìwé 2-3
  • Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2013

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2013
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jóṣúà 1:9—“Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára”
    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
  • Ohun Tí Jóṣúà Rántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Jẹ́ Onígboyà, Jèhófà Wà Pẹ̀lú Rẹ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ó Fẹ́ Ká Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2013
yb13 ojú ìwé 2-3

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2013

“Jẹ́ onígboyà àti alágbára. . . . Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ.” Jóṣúà 1:9

Ní ọdún 1473 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti múra láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àmọ́ àwọn ọ̀tá tó lágbára wà níwájú wọn. Ni Ọlọ́run bá pàṣẹ fún Jóṣúà pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára gidigidi.” Tí Jóṣúà bá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un, ó máa ṣàṣeyọrí. Jèhófà sọ fún un pé: “Má gbọ̀n rìrì tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí o bá lọ.” Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú rẹ̀ lóòótọ́, torí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn láàárín ọdún mẹ́fà péré.—Jóṣ. 1:7-9.

Àwa Kristẹni tòótọ́ máa tó wọnú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, torí náà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Bíi ti Jóṣúà, à ń kojú àwọn ọ̀tá alágbára tó ń wá ọ̀nà láti ba ìwà títọ́ wa jẹ́. Kì í ṣe ọ̀kọ̀ àti idà la fi ń wọ̀yá ìjà bí kò ṣe àwọn ohun ìjà ogun tẹ̀mí. Jèhófà sì ti kọ́ wa bá a ṣe lè lo àwọn ohun ìjà tẹ̀mí lọ́nà tó já fáfá. Ipò yòówù kó o bá ara rẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé tó o bá jẹ́ onígboyà àti alágbára, tó o sì jẹ́ olóòótọ́, Jèhófà á wà pẹ̀lú rẹ, á sì sọ ẹ́ di aṣẹ́gun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3]
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́