-
“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
10 Àpẹẹrẹ kan lohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Jẹ́fútà. Jèhófà jẹ́ káwọn ọmọ Ámónì fìyà jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún ọdún méjìdínlógún torí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà. Bíbélì sọ pé: “Wọ́n wá kó àwọn ọlọ́run àjèjì kúrò láàárín wọn, wọ́n sì ń sin Jèhófà, débi pé ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ bí Ísírẹ́lì ṣe ń jìyà.”b (Àwọn Onídàájọ́ 10:6-16) Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà látọkàn wá, ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́ kí ìyà ṣì máa jẹ wọ́n. Torí náà Ọlọ́run yọ́nú sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sì fún Jẹ́fútà lágbára láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-33.
-
-
“Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
b Gbólóhùn náà “ojú rẹ̀ ò gbà á mọ́” tún lè túmọ̀ sí pé kò lè ṣe sùúrù mọ́. Bíbélì Tanakh—A New Translation of the Holy Scriptures túmọ̀ rẹ̀ sí pé: “Kò lè fara dà á mọ́ kí ìyà máa jẹ Ísírẹ́lì.”
-