ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | July 1
    • Bí obìnrin méjèèjì yìí ṣe wá fìdí kalẹ̀ ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù bẹ̀rẹ̀ sí í ro bí òun ṣe máa rí ọ̀nà tó dáa jù tí òun lè gbà tọ́jú ara òun àti Náómì. Ó ti gbọ́ pé ètò onífẹ̀ẹ́ kan wà fún àwọn tálákà nínú Òfin tí Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. Òfin yẹn sọ pé wọ́n lè lọ sí oko nígbà ìkórè, kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn tó ń kórè lẹ́yìn ní pápá láti máa pèéṣẹ́, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa ṣa àwọn irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀, wọ́n sì tún lè máa kárúgbìn eteetí oko.c—Léfítíkù 19:9, 10; Diutarónómì 24:19-21.

      Ìgbà yẹn jẹ́ ìgbà ìkórè ọkà báálì, èyí tó máa bọ́ sí oṣù April ní ayé òde òní. Rúùtù wá jáde lọ sí pápá bóyá òun á rí ẹni gba òun láyè kí òun pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀. Àfi bó ṣe di pé oko ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan tó ń jẹ́ Bóásì ló ti ráyè pèéṣẹ́, Bóásì sì jẹ́ mọ̀lẹ́bí Elimélékì ọkọ Náómì tó ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lábẹ́ òfin, Rúùtù lẹ́tọ̀ọ́ láti pèéṣẹ́, síbẹ̀ kò kàn wọnú oko olóko, ṣe ló kọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin tó ń kó àwọn olùkórè ṣiṣẹ́. Ọkùnrin náà gbà á láyè, Rúùtù sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.—Rúùtù 1:22–2:3, 7.

  • “Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | July 1
    • c Òfin náà máa jọ Rúùtù lójú gan-an, torí kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Móábù tó ti wá. Láyé ìgbà yẹn, ní apá Ìlà Oòrùn, wọ́n máa ń fìyà jẹ àwọn opó. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Tí ọkọ obìnrin kan bá ti kú, àwọn ọmọkùnrin tí opó náà bí ló máa ń tọ́jú rẹ̀, tí kò bá sì ní ọmọkùnrin kankan, ó lè jẹ́ pé ṣe ló máa ní láti ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú tàbí kó di aṣẹ́wó tàbí kó kú.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́