ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | October 1
    • RÚÙTÙ kúnlẹ̀ níbi tí àwọn ìtí ọkà bálì tó ti ń ṣà jọ látàárọ̀ wà, láti bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ọkà náà. Ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní gbogbo àgbègbè ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ ní oko sì ti wà lọ́nà ilé nígbà yẹn, wọ́n rọra ń gòkè lọ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ lójú ọ̀nà tó wọ ẹnubodè ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ìyẹn ìlú kékeré tó wà lórí òkè nítòsí ibẹ̀. Ó dájú pé yóò ti rẹ Rúùtù gan-an torí iṣẹ́ tó ti ń ṣe bọ̀ látàárọ̀ láìfi bẹ́ẹ̀ sinmi. Síbẹ̀, ó tẹra mọ́ ọkà rẹ̀ tó ń pa, ó ń fi ọ̀pá lu àwọn ìtí ọkà náà kí ọkà inú rẹ̀ lè gbọ̀n jáde. Nǹkan ṣáà ti ṣẹnuure fún un, kódà ó tiẹ̀ tún kọjá bó ṣe lè retí pé ó máa dáa tó lọ́jọ́ náà.

  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | October 1
    • Nígbà tí Rúùtù pa ọkà náà tán, tó kó o jọ, ó rí i pé ọkà tí òun pèéṣẹ́ jẹ́ nǹkan bí òṣùwọ̀n eéfà kan ọkà bálì, ìyẹn nǹkan bí ìdajì àpò ìrẹsì. Ẹ ò rí i pé ẹrù gidi ni! Bóyá aṣọ ló tiẹ̀ fi dì í tó wá gbé e rù, tó sì gba ọ̀nà ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lọ bí oòrùn ṣe ń wọ̀.—Rúùtù 2:17.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́