-
“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
7, 8. (a) Ta ni Náómì gbà pé ó jẹ́ kí Bóásì ṣàánú Rúùtù? Kí nìdí tó fi gbà bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Rúùtù ṣe túbọ̀ fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìyá ọkọ rẹ̀?
7 Bí àwọn méjèèjì ṣe ń bá ọ̀rọ̀ lọ, Rúùtù sọ gbogbo bí Bóásì ṣe ṣàánú òun fún Náómì. Inú Náómì dùn gan-an, ó ní: “Ìbùkún ni fún un láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tí kò dẹ́kun inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ sí àwọn alààyè àti àwọn òkú.” (Rúùtù 2:20) Náómì gbà pé Jèhófà ló mú kí Bóásì ṣàánú Rúùtù, torí ó mọ̀ pé òun ló máa ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, tó sì ṣe ìlérí fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé òun á ṣàánú fún ẹni tó bá ń ṣàánú.a—Ka Òwe 19:17.
-
-
“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
a Bí Náómì ṣe sọ, kì í ṣe àwọn alààyè nìkan ni Jèhófà máa ń ṣàánú; ó máa ń rántí àwọn tó ti kú náà. Lọ́nà wo? Ọkọ Náómì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì ti kú. Ọkọ Rúùtù náà sì ti kú. Ó dájú pé àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe pàtàkì gan-an sí àwọn obìnrin méjèèjì. Torí náà, bí ẹnikẹ́ni bá ṣàánú Náómì àti Rúùtù, àwọn ọkùnrin yẹn ló ṣàánú fún. Ìdí ni pé bí wọ́n bá wà láàyè, wọn ò ní fẹ́ kí ìyà kankan jẹ àwọn obìnrin àtàtà yẹn.
b Ó dájú pé àwọn arákùnrin ẹni tó kú náà ni wọ́n máa ń kọ́kọ́ fún ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ opó náà. Tí wọn ò bá gbà láti ṣú u lópó ló tó lè kan mọ̀lẹ́bí rẹ̀ míì tó jẹ́ ọkùnrin. Bí wọ́n sì ṣe máa ṣe ogún rẹ̀ náà nìyẹn.—Núm. 27:5-11.
-
-
“Obìnrin Títayọ Lọ́lá”Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
11, 12. (a) Nígbà tí Náómì pe Bóásì ní “olùtúnnirà,” ìṣètò onífẹ̀ẹ́ wo ló ń tọ́ka sí nínú Òfin Ọlọ́run? (b) Kí ni Rúùtù ṣe nígbà tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ ohun tó máa ṣe fún un?
11 Ìgbà tí Rúùtù kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ Bóásì ni Náómì ti sọ pé: “Ọkùnrin náà bá wa tan. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùtúnnirà wa.” (Rúùtù 2:20) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn ìṣètò kan wà níbẹ̀ tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ àwọn ìdílé tí nǹkan nira fún torí pé wọ́n jẹ́ aláìní tàbí torí pé èèyàn wọn kan kú. Tí obìnrin kan ò bá tíì bímọ tí ọkọ rẹ̀ fi kú, inú rẹ̀ máa bà jẹ́ gan-an torí pé kò ní sí àtọmọdọ́mọ táá máa jẹ́ orúkọ ọkọ rẹ̀, irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ sì kú àkúrun nìyẹn. Àmọ́ Òfin Ọlọ́run gbà pé kí arákùnrin ẹni tó kú náà ṣú ìyàwó rẹ̀ lópó, kí obìnrin náà lè bí ọmọ tó máa di ajogún tí yóò máa jẹ́ orúkọ olóògbé náà, tí ohun ìní tí olóògbé náà fi sílẹ̀ á sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.b—Diu. 25:5-7.
-