ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | October 1
    • Bóásì wá ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Wàyí o, ọmọbìnrin mi, má fòyà. Gbogbo ohun tí o sọ ni èmi yóò ṣe fún ọ, nítorí gbogbo ẹni tí ó wà ní ẹnubodè àwọn ènìyàn mi mọ̀ pé ìwọ jẹ́ obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11) Inú rẹ̀ dùn nípa ọ̀rọ̀ fífi Rúùtù ṣe aya; bóyá kò sì yà á lẹ́nu bó ṣe sọ pé kí òun wá ṣe olùtúnnirà rẹ̀. Ṣùgbọ́n olódodo èèyàn ni Bóásì, nítorí náà kò kàn fúnra rẹ̀ yan ohun tó wù ú láti ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà. Ṣe ló sọ fún Rúùtù pé ẹlòmíì ṣì wà tó jẹ́ olùtúnnirà tó tan mọ́ ìdílé Náómì tímọ́tímọ́ ju òun lọ, pé òun máa kọ́kọ́ sọ fún onítọ̀hún, kí ó lè yàn bóyá òun máa fi Rúùtù ṣe aya.

  • “Obìnrin Títayọ Lọ́lá”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | October 1
    • Ẹ ò rí i pé ó máa dùn mọ́ Rúùtù gan-an tó bá tún ronú kan ohun tí Bóásì sọ nípa rẹ̀, pé “obìnrin títayọ lọ́lá” ni gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí! Ó sì dájú pé ara ohun tó jẹ́ kó lè ní irú orúkọ rere bẹ́ẹ̀ ni pé ó tara ṣàṣà láti mọ Jèhófà kó sì máa sìn ín. Ó tún lo inúure àti ẹ̀mí ìgbatẹnirò ńlá sí Náómì àti àwọn èèyàn rẹ̀ bí ó ṣe fínnúfíndọ̀ kọ́ àwọn àṣà àti ìṣe tó dájú pé ó ṣàjèjì sí i tẹ́lẹ̀, tó sì wá ń ṣe wọ́n. Tí a bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù àti ìgbàgbọ́ rẹ̀, a ó máa fi ọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n, a ó sì máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn àṣà àti ìṣe wọn. Àwa náà á sì wá dẹni tí àwọn èèyàn mọ̀ sí èèyàn dáadáa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́