-
Ó Hùwà Ọlọgbọ́nTẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
-
-
9, 10. (a) Abẹ́ ipò wo ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń wá jíjẹ mímu kiri? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí Nábálì mọyì oore tí Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń ṣe fún un? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó wà ní ìpínrọ̀ 10.)
9 Ìlú Máónì ni Nábálì ń gbé, àmọ́ ìlú Kámẹ́lì tí kò jìnnà sí Máónì ló ti ń ṣiṣẹ́, ó sì ṣeé ṣe kó nílẹ̀ síbẹ̀.a Nábálì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àgùntàn tó ń sìn láwọn ìlú tó wà níbi tó ga díẹ̀ yẹn. Ibẹ̀ dáa fún sísin àgùntàn torí pé koríko pọ̀ gan-an níbẹ̀. Àmọ́ aginjù ló yí wọn ká. Aginjù Páránì tó lọ súà wà lápá gúúsù àwọn ìlú náà. Aṣálẹ̀ tó dá páropáro tó sì kún fún àfonífojì tóóró àti àwọn hòrò ló wà lápá ìlà oòrùn lọ́nà ibi téèyàn máa gbà lọ sí Òkun Iyọ̀. Àgbègbè yìí ni Dáfídì àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti ń ṣe làálàá gidi kí wọ́n tó lè rí jíjẹ mímu wọn, ojú wọn sì ń rí màbo. Wọ́n sì sábà máa ń pàdé àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó ń da àwọn ẹran Nábálì ọlọ́rọ̀.
-