ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́—1997 | November 1
    • FÚN ọ̀dọ́ àgbẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Èlíṣà, ọjọ́ kan tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títúlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ ojoojúmọ́ di ọjọ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Bí ó ti ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ní pápá ni Èlíjà, wòlíì tí ó tayọ jù lọ ní Ísírẹ́lì, dé e lálejò láìròtẹ́lẹ̀. Èlíṣà ti lè ṣe kàyéfì pé, ‘Kí ni ó lè wá rí mi fún?’ Kò dúró pẹ́ kí ó tó rí èsì. Èlíjà ju ẹ̀wù oyè rẹ̀ sára Èlíṣà, ní fífihàn pé lọ́jọ́ kan, Èlíṣà yóò di arọ́pò òun. Èlíṣà kò fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìpè yí. Lójú ẹsẹ̀, ó fi pápá rẹ̀ sílẹ̀ láti di òjíṣẹ́ fún Èlíjà.—Àwọn Ọba Kìíní 19:19-21.

  • Àpẹẹrẹ Ìfara-Ẹni-Rúbọ àti Ìdúróṣinṣin
    Ilé Ìṣọ́—1997 | November 1
    • Nígbà tí a nawọ́ ìkésíni láti ṣe iṣẹ́ ìsìn àkànṣe pẹ̀lú Èlíjà sí i, ojú ẹsẹ̀ ni Èlíṣà fi pápá rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìránṣẹ́ fún wòlíì títayọ jù lọ ní Ísírẹ́lì. Ó hàn kedere pé, díẹ̀ nínú iṣẹ́ rẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú, nítorí a mọ̀ ọ́n sì ẹni tí ó “ń tú omi sí ọwọ́ Èlíjà.”c (Àwọn Ọba Kejì 3:11) Síbẹ̀síbẹ̀, Èlíṣà wo iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àǹfààní kan, ó sì fi ìdúróṣinṣin dúró ti Èlíjà gbágbágbá.

      Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ń fi irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ hàn. Àwọn kan ti fi “pápá” wọn, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, sílẹ̀, láti wàásù ìhìn rere ní àwọn ìpínlẹ̀ jíjìnnà réré tàbí láti sìn gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Àwọn mìíràn ti rìnrìn àjò lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè láti ṣiṣẹ́ ní àwọn ibi iṣẹ́ ìkọ́lé ti Society. Ọ̀pọ̀ ti tẹ́wọ́ gba ohun tí a lè pé ní iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọjú. Síbẹ̀, kò sí ẹni tí ń sin Jèhófà tí iṣẹ́ rẹ̀ kò ṣe pàtàkì. Jèhófà mọyì gbogbo àwọn tí ó bá fi tinútinú sìn ín, yóò sì bú kún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn.—Máàkù 10:29, 30.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́