-
Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?Ilé Ìṣọ́—2013 | August 15
-
-
OHUN TÍ ÈLÍṢÀ RÍ
Báwo ló ṣe rí lára Ọlọ́run nígbà tí Èlíṣà béèrè fún ipa méjì nínú ẹ̀mí Èlíjà? Àkọsílẹ̀ yẹn kà pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí wọ́n ti ń rìn lọ, tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti ń rìn, họ́wù, wò ó! kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná kan àti àwọn ẹṣin oníná, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pààlà sáàárín àwọn méjèèjì; Èlíjà sì gòkè re ọ̀run nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù. Ní gbogbo àkókò náà, Èlíṣà rí i.”a Bí Jèhófà ṣe dá Èlíṣà lóhùn nìyẹn o! Ó rí i bí a ṣe gba Èlíjà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì tún gba ìlọ́po méjì ẹ̀mí Èlíjà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ajogún tẹ̀mí fún wòlíì náà.—2 Ọba 2:11-14.
-
-
Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?Ilé Ìṣọ́—2013 | August 15
-
-
Ó dájú pé ohun tí Èlíṣà rí nígbà tí Èlíjà gòkè re ọ̀run nínú ìjì ẹlẹ́fùúùfù nípa lórí rẹ̀ gan-an. Kì í ṣáà ṣe ojoojúmọ́ lèèyàn ń rí kẹ̀kẹ́ ogun oníná àti àwọn ẹṣin oníná! Torí náà, ńṣe ni èyí jẹ́ ẹ̀rí pé inú Jèhófà dùn sí ohun tí Èlíṣà béèrè. Òótọ́ ni pé tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà wa, a kì í rí ìran kẹ̀kẹ́ ogun oníná àti àwọn ẹṣin oníná. Àmọ́, a máa ń fòye mọ̀ pé Jèhófà ń lo agbára ńlá rẹ̀ láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Nígbà tá a bá sì rí i pé Jèhófà ń bù kún apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tí à ń fojú wa “rí” kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run Jèhófà tó wà lẹ́nu iṣẹ́.—Ìsík. 10:9-13.
-
-
Èlíṣà Rí Kẹ̀kẹ́ Ẹṣin Oníná—Ṣé Ìwọ Náà Rí I?Ilé Ìṣọ́—2013 | August 15
-
-
a Èlíjà kò gòkè re àwọn ọ̀run tó jẹ́ ibi ẹ̀mí tí Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ń gbé. Wo Ilé Ìṣọ́ September 15, 1997, ojú ìwé 15.
-