-
“Olùgbọ́ Àdúrà”Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
ṢÉ ÒÓTỌ́ ni pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà àtọkànwá àwọn olóòótọ́ tó ń sìn ín? Ìtàn inú Bíbélì nípa ọkùnrin kan tí a kò mọ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jábésì fi hàn pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ àdúrà” ní tòótọ́. (Sáàmù 65:2) Àkọsílẹ̀ kúkúrú yìí la rí níbi tí a kò fọkàn sí, ìyẹn nínú àkọsílẹ̀ àwọn ìlà ìdílé tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Kíróníkà Kìíní. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò 1 Kíróníkà 4:9, 10.
-
-
“Olùgbọ́ Àdúrà”Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
Jábésì jẹ́ ẹni tó máa ń gbàdúrà gan-an. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ ni pé kí Ọlọ́run bù kún òun. Lẹ́yìn náà, ó béèrè ohun mẹ́ta tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára.
Ohun àkọ́kọ́ tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé: “Sọ ìpínlẹ̀ mi di títóbi.” (Ẹsẹ 10) Ọkùnrin ọlọ́lá yìí kì í ṣe ẹni tó lójú kòkòrò láti gba ilẹ̀ sí i, kì í ṣe ẹni tójú rẹ̀ ń wọ ohun ìní ẹlòmíì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí àwọn èèyàn ló ṣe gbàdúrà àtọkànwá, kì í ṣe torí kó lè ní ilẹ̀. Ó lè jẹ́ pé àdúrà rẹ̀ ni pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí ìpínlẹ̀ òun pọ̀ sí i láìsí pé òun jagun, kí àwọn èèyàn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ bàa lè pọ̀ sí i níbẹ̀.b
Ohun kejì tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé, kí “ọwọ́” rẹ̀ wà pẹ̀lú òun. Ọwọ́ Ọlọ́run ṣàpẹẹrẹ agbára rẹ̀, tí ó ń lò láti fi ran àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́wọ́. (1 Kíróníkà 29:12) Ojú Ọlọ́run tí ọwọ́ rẹ̀ kò kúrú láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó gbà á gbọ́ ni Jábésì ń wò, kó lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè ọkàn rẹ̀.—Aísáyà 59:1.
Ohun kẹta tí Jábésì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ni pé: “Pa mí mọ́ . . . kúrò nínú ìyọnu àjálù, kí ó má bàa ṣe mí lọ́ṣẹ́.” Gbólóhùn náà, “kí ó má bàa ṣe mí lọ́ṣẹ́” lè fi hàn pé kì í ṣe pé Jábésì ń gbàdúrà pé kóun má ṣe rí àjálù, àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé kí àjálù má ṣe dorí òun kodò tàbí borí òun.
Àdúrà Jábésì fi èrò rẹ̀ nípa ìjọsìn tòótọ́ hàn, ó sì tún fi ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ nínú Olùgbọ́ àdúrà hàn. Kí ni Jèhófà ṣe? Àwọn ọ̀rọ̀ tó parí àkọsílẹ̀ kúkúrú yìí sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Ọlọ́run mú ohun tí ó béèrè ṣẹ.”
Olùgbọ́ àdúrà kò tíì yí pa dà. Inú rẹ̀ ń dùn sí àdúrà àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. Ó dá àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ lójú pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”—1 Jòhánù 5:14.
-
-
“Olùgbọ́ Àdúrà”Ilé Ìṣọ́—2010 | October 1
-
-
b Ìwé Targum, ìyẹn ìwé táwọn Júù fi ṣàlàyé Ìwé Mímọ́, túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jábésì báyìí pé: “Fi àwọn ọmọ bù kún mi, kí o sì jẹ́ kí ààlà mí gbòòrò sí i, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i níbẹ̀.”
-