“Ta Ní Bí Ìrì Tí Ń Sẹ̀?”
ONÍRÒYÌN kan ní ọ̀rúndún kọkàndílógún ṣàpèjúwe ìrì bí “ohun ọ̀ṣọ́ olómi ti ilẹ̀ ayé, tí ń wá láti inú atẹ́gùn.” Ẹlẹ́dàá wa bi baba ńlá náà, Jóòbù, léèrè pé: “Ta ní bí ìrì tí ń sẹ̀?” (Jóòbù 38:28) Ọlọ́run ń rán Jóòbù létí pé ọ̀run ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìrì ṣíṣeyebíye náà wà.
Yàtọ̀ sí ẹwà tí ó jọ ohun ọ̀ṣọ́, tí ń dán gbinrin tí ìrì ní, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì, a máa ń so ó pọ̀ mọ́ ìbùkún, ìlèbímọ, ọ̀pọ̀ yanturu nǹkan, àti dídá ẹ̀mí sí. (Jẹ́nẹ́sísì 27:28; Diutarónómì 33:13, 28; Sekaráyà 8:12) Ní ìgbà tí ooru mú, tí òjò kò sì rọ̀ ní Ísírẹ́lì, “ìrì Hámónì” jẹ́ kí àwọn ewéko ilẹ̀ náà, àti àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú máa wà nìṣó. Òkè Hámónì tí igbó àti òjò dídì bo orí rẹ̀ ṣì ń mú oruku, tí ń dì, tí ó sì ń sẹ̀ bí ìrì tí ó pọ̀, wá lóru. Onísáàmù náà, Dáfídì, fi ìtura tí ìrì yìí ń mú wá wé ìrírí gbígbádùnmọ́ni tí ó wà nínú gbígbépọ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí ń jùmọ̀ sin Jèhófà.—Sáàmù 133:3.
Àwọn ìtọ́ni tí wòlíì Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pẹ̀lẹ́, ó sì ń tuni lára bí ìrì tí ń sẹ̀. Ó sọ pé: “Àsọjáde mi yóò máa sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ìrì, bí òjò winniwinni sára koríko àti bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò sára ewéko.” (Diutarónómì 32:2) Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìyè dé ìkangun ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:14) Ọlọ́run ń ké síni pé: “‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ń gba ìkésíni yìí fún ìtura tẹ̀mí, tí ó lè gbé ìwàláàyè ró títí ayérayé, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.