-
Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ JèhófàGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
Ẹ̀KỌ́ 08
Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà
Jèhófà fẹ́ kó o túbọ̀ mọ òun. Kí nìdí? Ìdí ni pé bó o bá ṣe ń mọ ìwà àti ìṣe Jèhófà sí i, tí ò ń mọ bó ṣe ń ṣe nǹkan, àtohun tó fẹ́ ṣe fáwa èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. Ṣé o gbà pé o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (Ka Sáàmù 25:14.) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ó sì tún sọ ìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.
1. Kí ni Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe?
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) Kí ni ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí? Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o di ọ̀rẹ́ òun. Àwọn kan gbà pé ó máa ṣòro gan-an láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run torí pé àwa èèyàn ò lè rí Ọlọ́run. Síbẹ̀, nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa ìwà àti ìṣe òun ká lè sún mọ́ ọn. Tá a bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì, ọ̀rẹ́ àwa àti Jèhófà á máa jinlẹ̀ sí i, bá ò tiẹ̀ rí i.
2. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ?
Kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ rẹ tó bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ó fẹ́ kó o máa láyọ̀, kó o sì máa gbàdúrà sí òun nígbàkigbà tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́. Torí náà, ‘máa kó gbogbo àníyàn rẹ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ torí ó ń bójú tó ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Jèhófà múra tán láti ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó múra tán láti tù wọ́n nínú, ó sì máa ń tẹ́tí sí wọn.—Ka Sáàmù 94:18, 19.
3. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, “ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kí wọ́n sì máa sá fún ìwà burúkú. Àwọn kan rò pé agbára àwọn ò lè gbé e láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Sáàmù 147:11; Ìṣe 10:34, 35.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o sì mọ ìdí tó fi jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ.
4. Ọ̀rẹ́ Jèhófà ni Ábúráhámù
Ìtàn Ábúráhámù (tó tún ń jẹ́ Ábúrámù) nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Kà nípa Ábúráhámù ní Jẹ́nẹ́sísì 12:1-4. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà sọ pé kí Ábúráhámù ṣe?
Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù?
Kí ni Ábúráhámù ṣe nígbà tí Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà?
5. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ òun máa ṣe
A sábà máa ń retí kí àwọn ọ̀rẹ́ wa ṣe àwọn ohun kan fún wa.
Àwọn nǹkan wo lo fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún ẹ?
Ka 1 Jòhánù 5:3, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?
Ká lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yí ìwà wa tàbí ìṣe wa pa dà. Ka Àìsáyà 48:17, 18, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe àwọn àyípadà kan?
Ohun tó máa dáàbò bò wá ni ọ̀rẹ́ gidi máa ń sọ pé ká ṣe, ó sì máa ń gbà wá nímọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní. Ohun kan náà ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀
6. Bí Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́
Jèhófà máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.
Báwo ni Jèhófà ṣe ran obìnrin tó wà nínú fídíò yìí lọ́wọ́ kó lè borí èrò tí ò tọ́ àti ẹ̀dùn ọkàn?
Ka Àìsáyà 41:10, 13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún àwọn ọ̀rẹ́ òun?
Ṣó o rò pé ọ̀rẹ́ tó dáa ni Jèhófà? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá nílò ìrànwọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́
7. Tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, o gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, kó o sì máa tẹ́tí sí i
Bí àwọn ọ̀rẹ́ bá ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tó ni wọ́n á ṣe túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ka Sáàmù 86:6, 11, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ọ̀nà wo la lè gbà bá Jèhófà sọ̀rọ̀?
Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà bá wa sọ̀rọ̀?
A máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà, òun náà sì máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”
Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà láti fi hàn pé a lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Jèhófà fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Kí lo rí kọ́?
Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́?
Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe àwọn àyípadà kan?
Ṣó o rò pé Jèhófà ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ rẹ kó o tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
“Jèhófà—Ọlọ́run Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dáadáa” (Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003)
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
Kà nípa bí ìgbésí ayé obìnrin kan ṣe dáa gan-an torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà.
Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ nípa Jèhófà.
-
-
Ìrìbọmi Ṣe Pàtàkì!Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
6. Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, ó ti di ara ìdílé Jèhófà nìyẹn
Tá a bá ti ṣèrìbọmi, a ti di ara ìdílé kan tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la ti wá, bí wọ́n sì ṣe tọ́ wa dàgbà yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ohun kan náà la gbà gbọ́, ìlànà ìwà rere kan náà la sì ń tẹ̀ lé. Ka Sáàmù 25:14 àti 1 Pétérù 2:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tẹ́nì kan bá ti ṣèrìbọmi, báwo ni àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn tá a jọ ń sin Jèhófà ṣe máa rí?
-
-
Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé tó dáa ní báyìí?
Jèhófà dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá láti wá “ìtọ́sọ́nà” rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń fẹ́ láti mọ̀ ọ́n, ká sì máa jọ́sìn rẹ̀. (Ka Mátíù 5:3-6.) Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun dáadáa, ká máa “rìn ní gbogbo ọ̀nà” òun, ká máa “nífẹ̀ẹ́” òun, ká sì máa sin òun pẹ̀lú “gbogbo ọkàn” wa. (Diutarónómì 10:12; Sáàmù 25:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ayọ̀ tòótọ́, láìka àwọn ìṣòro wa sí. Tá a bá ń sin Jèhófà, ayé wa máa dáa, ọkàn wa sì máa balẹ̀.
-