ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” Laaarin Awọn Ọta
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
    • 4-6. (a) Bawo ni Orin Dafidi 2 bẹẹ gẹgẹ ṣe fihan pe Jesu ki yoo nilati duro de iyilọkanpada agbaye ṣaaju bibẹrẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia”? (b) Nigba wo ni Orin Dafidi 2:7 ní imuṣẹ?

      4 O ṣe kedere, nigba naa pe, Jesu Kristi, gẹgẹ bi Ọmọkunrin Dafidi, ni ki yoo bẹrẹ iṣakoso rẹ̀ lẹhin iyilọkanpada agbaye. Kakabẹẹ, oun yoo bẹrẹsii ṣakoso laaarin awọn ọta rẹ̀ awọn ẹni ti Jehofa Ọlọrun nipasẹ ogun jija yoo sọ di apoti itisẹ ní asẹhinwa-asẹhinbọ fun ẹsẹ Ọmọkunrin rẹ̀ ti a ti gbeka ori itẹ. Bẹẹ gẹgẹ Orin Dafidi 2 (NW), ninu awọn ọ̀rọ̀ ti wọn tẹ̀lé e wọnyi, fi ibẹrẹ iṣakoso rẹ̀ gẹgẹ bi “Ọmọ-Aládé Alaafia” laaarin awọn ọta han:

      5 “Eeṣe ti awọn orilẹ-ede fi wà ninu ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ti awọn awujọ orilẹ-ede funraawọn si ń baa lọ́ ní sisọrọ nǹkan ofifo ní kẹlẹkẹlẹ? Awọn ọba ilẹ̀-ayé mu iduro wọn awọn ijoye oṣiṣẹ giga funraawọn si ti kojọpọ gẹgẹ bi ọkanṣoṣo lodisi Jehofa ati lodisi ẹni ami-ororo rẹ̀ [Kristi rẹ̀], ní wiwi pe: ‘Ẹ jẹ́ ki a já awọn ìdè wọn sọtọọtọ ki a si ju awọn okun wọn nù kuro lọdọ wa!’ Ẹni naa gan-⁠an ti ó jokoo ninu awọn ọ̀run yoo rẹrin-in; Jehofa fúnraarẹ̀ yoo fi wọn ṣẹsin. Ní akoko naa oun yoo sọrọ si wọn ninu ibinu rẹ̀ oun yoo si yọ wọn lẹnu ninu ibinu rẹ̀, ní wiwi pe: ‘Emi, ani emi, ti fi ọba mi sori oyè lori Sioni, oke-nla mímọ́ mi.’

  • Iṣakoso “Ọmọ-Aládé Alaafia” Laaarin Awọn Ọta
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
    • 7. Itọka wo si Orin Dafidi 2 ni awọn aposteli Jesu Kristi ṣe lẹhin ọjọ Pentekosti?

      7 Gẹgẹ bi Iṣe 4:​24-⁠27 (NW) ti wi, awọn aposteli Jesu Kristi tọkasi Orin Dafidi 2 yii lẹhin ọjọ Pentekosti, 33 C.E.: “Pẹlu iṣọkan wọn gbe ohun wọn soke si Ọlọrun wọn si wi pe: ‘Oluwa Ọba-alaṣẹ, iwọ ni Ẹni naa ti ó ṣẹ̀dá ọ̀run ati ilẹ̀-ayé ati okun ati gbogbo ohun ti ń bẹ ninu wọn, ati ẹni ti o tipasẹ ẹmi mímọ́ wi lati ẹnu Dafidi babanla wa, iranṣẹ rẹ pe, “Eeṣe ti awọn orilẹ-ede fi ń rọ́kẹ̀kẹ̀ ti awọn eniyan si ń ṣàṣàrò lori awọn ohun asan? Awọn ọba ilẹ̀-ayé mu iduro wọn awọn oluṣakoso si kojọpọ gẹgẹ bi ọkan lodisi Jehofa ati ẹni ami-ororo rẹ̀.” Ani bẹẹ gẹgẹ, ati Herodu ati Pontiu Pilatu pẹlu awọn eniyan awọn orilẹ-ede ati pẹlu awọn eniyan Israeli ni wọn kojọpọ nitootọ ninu ilu-nla yii lodisi Jesu iranṣẹ mímọ́ rẹ, ẹni ti iwọ fororo yàn.’”

      Imuṣẹ Titobiju Ti Orin Dafidi 2

      8. (a) Nigba wo ni imuṣẹ akọkọ ti Orin Dafidi 2:​1, 2 ṣẹlẹ? (b) Lati igba wo ni imuṣẹ titobiju ti Orin Dafidi 2 ti ń ṣẹlẹ?

      8 Ni ọdun 33 ti ọrundun kìn-ín-ní ni awọn ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ wọnyẹn ti Orin Dafidi 2:​1, 2 kọ́kọ́ ní imuṣẹ. Eyi jẹ́ ní isopọ pẹlu ọkunrin naa Jesu Kristi lori ilẹ̀-ayé. Oun ni a ti fororo yàn pẹlu ẹmi mímọ́ Jehofa ní akoko baptisi rẹ̀ nipasẹ Johannu Arinibọmi. Ṣugbọn imuṣẹ titobiju ti Orin Dafidi 2 ti ń ṣẹlẹ lati igba opin Akoko Awọn Keferi ní ọdun 1914. (Luku 21:24) A ti jẹrii sii lẹkun-unrẹrẹ pe “akoko awọn Keferi,” eyi ti ó bẹrẹ nigba iparun akọkọ ti ilu Jerusalemu ní 607 B.C.E., dopin ní ọdun 1914.a Nigba naa ni agogo iku ró fun awọn orilẹ-ede agbaye, titikan awọn ti Kristẹndọm.

      9. Ki ni ṣẹlẹ nigba iparun akọkọ Jerusalemu ní isopọ pẹlu Ijọba Ọlọrun eyi ti ìlà ọlọba ti Ọba Dafidi ṣoju fun?

      9 Nigba iparun akọkọ Jerusalemu, lati ọwọ́ awọn ara Babiloni, Ijọba Jehofa Ọlọrun lori orilẹ-ede Israeli, eyi ti ìlà ọlọba ti Ọba Dafidi ń ṣoju fun, wá sí ipari. Lati igba naa wa, awọn Ju abinibi kò tii ní ọba kankan lori wọn lati ìlà ile ọlọba ti Dafidi. Ṣugbọn Ijọba Ọlọrun Ọga Ogo ní ọwọ́ atọmọdọmọ Dafidi kan, ẹni ti Jehofa bá dá majẹmu kan fun Ijọba ainipẹkun ní ìlà rẹ̀, kì yoo wà bẹẹ laigberi mọ́ lori ilẹ̀-ayé titi lae.

      10, 11. (a) Ki ni Ọlọrun sọ nipasẹ wolii rẹ̀ Esekieli ní isopọ pẹlu itẹ Dafidi? (b) Ta ni ó wá sori itẹ Dafidi pẹlu “ẹ̀tọ́ ofin”? (c) Ki ni ogunlọgọ awọn Ju sọ nigba ti o fi araarẹ̀ han gẹgẹ bi ajogun lọna ofin?

      10 Kete ṣaaju iparun rẹ̀ akọkọ, Jehofa mu ki wolii rẹ̀ Esekieli dari awọn ọ̀rọ̀ wọnyi si ọba Jerusalemu igbaani pe: “Ati iwọ, aláìlọwọ̀ ẹni buburu ọmọ-alade Israeli, ẹni ti ọjọ rẹ̀ de, nigba aiṣedeede ikẹhin. Bayii ni Oluwa Ọlọrun wi; Mu fìlà ọba kuro, sì ṣí ade kuro: eyi kò ni jẹ́ ọkan naa; gbe ẹni ti ó rẹlẹ ga, sì rẹ ẹni ti ó ga silẹ. Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì í ṣubu, ki yoo sì sí mọ́, titi igba ti ẹni ti ó [ni ẹ̀tọ́ ofin si i, NW] bá de; emi o si fi fun un.”​—⁠Esekieli 21:​25-⁠27.

      11 Ẹni naa ti ó ní “ẹ̀tọ́ ofin si i” wá oun sì ni Jesu Kristi, ìlà atirandiran rẹ̀ lati ọdọ Dafidi ni a sì kọ silẹ ninu Matteu 1:​1-⁠16 ati Luku 3:​23-⁠31. Oun ni a saba maa ń pe ní “Ọmọ Dafidi.” Ní ọjọ igun kẹtẹkẹtẹ alayọ iṣẹgun rẹ̀ wọnu Jerusalemu, ti ó gun ori kẹtẹkẹtẹ ní imuṣẹ asọtẹlẹ, ogunlọgọ awọn Ju ti wọn ń yọ ayọ̀ aṣeyọri ti wọn ń bá oun ati awọn aposteli rẹ̀ rin lọ́ kejade pẹlu ìhó ayọ̀ pe: “Hosanna fun Ọmọ Dafidi: Olubukun ni ẹni ti o ń bọ̀ wá ní orukọ Oluwa; Hosanna loke ọ̀run.”​—⁠Matteu 21:⁠9.

      A Gbé “Ọmọ Dafidi” Ka Ori Itẹ Ní Ọrun

      12. Nigba ti Akoko Awọn Keferi dopin ní 1914, nibo ni a ti gbé Jesu Kristi ka ori itẹ, gẹgẹ bi ajogun Dafidi wíwà titilọ?

      12 Ọdun 2,520 naa fun awọn Keferi lati maa tẹ Ijọba Ọlọrun ti ó wa ní ọwọ́ idile Dafidi mọlẹ labẹ atẹlẹsẹ wọn dopin ní 1914. Nigba naa ní akoko dé fun Jesu Kristi, “Ọmọ Dafidi,” lati di ẹni ti a gbé ka ori itẹ, kii ṣe nisalẹ nihin-⁠in lori itẹ ti ilẹ̀-ayé, ṣugbọn ninu awọn ọ̀run gigajulọ ní ọwọ́ ọtun Jehofa Ọlọrun!​—⁠Danieli 7:​9, 10, 13, 14.

      13. (a) Lati ọdun wo ni a ti tọka ṣaaju si ọdun 1914 gẹgẹ bi opin Akoko Awọn Keferi, nipasẹ ta sì ni? (b) Ki ni iṣarasihuwa awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé si “Ọmọ Dafidi” ti a ṣẹṣẹ gbeka ori itẹ yii?

      13 Ọdun manigbagbe yẹn ni awọn wọnni ti wọn di alabaakẹgbẹpọ Watch Tower Bible and Tract Society ti tọkasi ṣaaju lati 1876 wá. Ṣugbọn awọn orilẹ-ede ilẹ̀-ayé, ati awọn wọnni ti wọn jẹ́ ti Kristẹndọm paapaa, kọ̀ lati gba a gẹgẹ bi akoko fun wọn lati fi awọn ipo ọba-alaṣẹ wọn ti ilẹ̀-ayé fun “Ọmọ Dafidi” ti a ṣẹṣẹ gbeka ori itẹ. Wọn kò gbà pe oun ní ẹtọ ti Ọlọrun fifun un si ipo ọba-alaṣẹ lori gbogbo ilẹ̀-ayé, eyi ti ó jẹ́ apoti itisẹ Jehofa Ọlọrun. (Matteu 5:35) Wọn fami sọ fífi ti wọn fi ọdaju pa Ọba titọna naa tì nipa kikowọnu ogun agbaye kìn-ín-⁠ní.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́