-
Ẹ Duro Pẹkipẹki Ti JehofaIlé-Ìṣọ́nà—1991 | December 15
-
-
1. Ki ni ifẹ-inu Jehofa nipa adura, iṣiri wo ni apọsiteli Pọọlu sì fi funni nipa gbigbadura?
JEHOFA ni ‘Ọlọrun ti nfi ireti fun’ gbogbo awọn eniyan rẹ̀ oluṣotitọ. Gẹgẹ bi “Olugbọ adura,” oun nfetisilẹ si awọn ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ wọn fun iranlọwọ lati jere ireti alayọ ti ó gbé ka iwaju wọn. (Roomu 15:13; Saamu 65:2, NW) Ati nipasẹ Ọrọ rẹ̀, Bibeli, ó fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ niṣiiri lati wá si ọdọ rẹ̀ nigbakigba ti wọn bá fẹ. Oun wà nibẹ nigba gbogbo, ni fifẹ lati gba aniyan inu lọhun-un julọ wọn. Nitootọ, o fun wọn niṣiiri lati “ni iforiti ninu adura” ati lati “maa gbadura laisinmi.”a (Roomu 12:12; 1 Tẹsalonika 5:17, NW) Ó jẹ́ ifẹ-inu Jehofa pe ki gbogbo awọn Kristẹni maa ké pe e ninu adura ni gbogbo ìgbà, ni titu ọkan-aya wọn jade si i ati ni ṣiṣe bẹẹ ni orukọ Ọmọkunrin rẹ̀ olufẹ ọwọn, Jesu Kristi.—Johanu 14:6, 13, 14.
-
-
Ẹ Duro Pẹkipẹki Ti JehofaIlé-Ìṣọ́nà—1991 | December 15
-
-
3 Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kọwe pe: “Ẹ sunmọ Ọlọrun, oun yoo sì sunmọ yin.” (Jakobu 4:8) Bẹẹni, Ọlọrun kò ga fiofio ju tabi jinna ju lati gbọ awọn ọrọ ti a darí si i, laika ipo aipe eniyan wa sí. (Iṣe 17:27) Siwaju sii, oun kii ṣe onídàágunlá ati aláìbìkítà. Onisaamu naa wi pe: “Oju Oluwa [“Jehofa,” NW] nbẹ lara awọn olododo, eti rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn.”—Saamu 34:15; 1 Peteru 3:12.
4. Bawo ni a ṣe lè ṣakawe itẹtisilẹ Jehofa si adura?
4 Jehofa beere fun adura. A lè fi eyi wé ipejọpọ kan nibi ti awọn eniyan ti ó pọ ti nba araawọn sọrọ. Iwọ wà nibẹ, ni fifeti silẹ si bi awọn ẹlomiran ti nsọrọ. Ipa tirẹ jẹ ti ẹni ti nṣakiyesi. Ṣugbọn lẹhin naa ẹnikan yiju si ọ, ó pe orukọ rẹ, o sì doju awọn ọrọ rẹ kọ ọ. Eyi gba afiyesi rẹ ni ọna akanṣe kan. Bakan naa, Ọlọrun ntẹtisilẹ nigba gbogbo si awọn eniyan rẹ̀, nibikibi yoowu ki wọn wà. (2 Kironika 16:9; Owe 15:3) Nitori naa oun ngbọ awọn ọrọ wa, ni kikiyesi lọna idaabobo ati lọna onifẹẹ, gẹgẹ bi a ti lè sọ ọ. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a bá kepe orukọ Ọlọrun ninu adura, afiyesi rẹ̀ ni a gbà, oun si pa afiyesi pọ si wa nisinsinyi ni ọna ti ó ṣe kedere. Nipa agbara rẹ̀, Jehofa tilẹ lè ṣawari ki ó si mọ adura ẹ̀bẹ̀ ti a ko sọ jade ti eniyan gbà ninu awọn ibi kọlọfin ti o farasin ninu ọkan-aya ati ero-inu rẹ̀. Ọlọrun mu un da wa loju pe oun yoo fà sunmọ gbogbo awọn wọnni ti wọn fi otitọ inu kepe orukọ rẹ ti wọn sì nwa ọna lati duro pẹkipẹki ti i.—Saamu 145:18.
-