“Ẹlẹ́rìí Aṣeégbíyèlé ní Sánmà”
Ó PẸ́ táwọn akéwì àtàwọn akọrin ti máa ń fi oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ pọ́n òṣùpá nítorí ẹwà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, orin kan tí Ọlọ́run mí sí sọ nípa obìnrin kan tó “lẹ́wà bí òṣùpá àrànmọ́jú.” (Orin Sólómọ́nì 6:10) Onísáàmù kan tún fi ewì sọ pé òṣùpá jẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà.” (Sáàmù 89:37) Kí lohun tó sọ yìí túmọ̀ sí?
Ọjọ́ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àti wákàtí mẹ́jọ ni òṣùpá fi máa ń yí ayé po, ìgbà tó fi ń yí po yìí kì í sì í yẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí onísáàmù náà sọ pé òṣùpá jẹ́ aṣeégbíyèlé, ìyẹn lè túmọ̀ sí pé ó ṣeé gbára lé. Àmọ́ ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ jùyẹn lọ ni onísáàmù náà ní lọ́kàn. Ó pe òṣùpá ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé” nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tó kọ lórin nípa Ìjọba tí Jésù ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà pé kó dé.—Mátíù 6:9, 10.
Ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn ni Jèhófà Ọlọ́run bá Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un dá májẹ̀mú Ìjọba yẹn. (2 Sámúẹ́lì 7:12-16) Ìdí tó fi bá Dáfídì dá májẹ̀mú yẹn ni pé kí Jésù Kristi tó jẹ́ ajogún Dáfídì lè láṣẹ láti jogún ìtẹ́ náà títí ayé lọ́nà tó bófin mu. (Aísáyà 9:7; Lúùkù 1:32, 33) Nígbà tí onísáàmù náà ń sọ̀rọ̀ nípa ìtẹ́ “irú-ọmọ” Dáfídì náà, ó kọ ọ́ lórin pé: “A ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in gẹ́gẹ́ bí òṣùpá fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà.”—Sáàmù 89:36, 37.
Nípa bẹ́ẹ̀, bá a ṣe ń rí òṣùpá tó jẹ́ ‘orísun ìmọ́lẹ̀ tó ń jọba lórí òru,’ ó ń rán wa létí pé títí gbére ni Kristi máa ṣàkóso. (Jẹ́nẹ́sísì 1:16) Dáníẹ́lì 7:14 sọ nípa Ìjọba Kristi pé: “Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.” Òṣùpá jẹ́ ẹlẹ́rìí tó ń rán wa létí Ìjọba yẹn àti bó ṣe máa bù kún aráyé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Òṣùpá:Fọ́tò NASA