“Ẹlẹ́rìí Otitọ Ni Ọ̀run”
TIPẸTIPẸ ṣaaju ki ọkunrin akọkọ tó rìn lori ilẹ̀-ayé, ni oṣupa ti ń tàn rokoso lálẹ́ loju ọrun. Ni akoko kan ọpọlọpọ jọsin rẹ̀ gẹgẹ bi abo ọlọrun. Onkọwe Griki naa Plutarch jẹwọ pe oṣupa ni opin àjò ọkàn alailabawọn lẹhin iku. Ninu ẹkọ nipa arosọ atọwọdọwọ Baltic oṣupa jẹ́ ọkunrin kan, ọkọ òòrùn. Wọn ni ìjà lọkọlaya, oṣupa si sakuro lọdọ aya rẹ̀, ni fifarahan pẹlu rẹ̀ ninu awọn ọrun!
Lonii, awọn ọ̀dọ́ ololufẹ—ati awọn ti wọn kìí fi bẹẹ ṣe ọ̀dọ́—ń wo oṣupa wọn sì ń ro awọn ero elere-ifẹ. Ni awọn ọdun 1960 awọn onimọ ijinlẹ ná iye owo ti o gadabu lati mu ki awọn eniyan ṣiṣẹ lori oṣupa ki wọn sì mú iwọn okuta diẹ pada wá fun iwadii. Ohun kan nipa oṣupa daju. Ni ọjọ kọọkan, gẹ́lẹ́ ni akoko rẹ̀, yoo ràn yoo sì wọ̀. O jẹ́ olotiitọ tobẹẹ gẹẹ ninu iyikaakiri rẹ̀ ti a yàn fun un debi pe a lè ka awọn ipele idagbasoke ati iṣokunkun rẹ̀ ni awọn ẹgbẹẹgbẹrun ọdun ti o ti kọja lọ.
Nigba ti awọn ọmọ Israeli bá wo oṣupa, a rán wọn leti ohun kan ti o jẹ́ agbayanu. Ọlọrun ṣeleri pe ila idile ọlọba ti Ọba Dafidi ni kì yoo parun. O sọ pe: “A o fi idi rẹ̀ [iru ọmọ Dafidi] mulẹ laelae bi oṣupa, ati bi ẹlẹrii otitọ ni ọrun.” (Orin Dafidi 89:35-37) Ileri yii ni a muṣẹ ninu Jesu, “Ọmọ Dafidi.” (Luku 18:38) Lẹhin iku rẹ̀ Jesu ni a ji dide gẹgẹ bi ẹmi alaileku ti o si goke re ọrun. (Iṣe 2:34-36) Bi akoko ti ń lọ oun ni a gbé gorí ìtẹ́ gẹgẹ bi Ọba Ijọba ọrun ti Ọlọrun. (Ìfihàn 12:10) Ijọba yẹn ti ń ṣakoso nisinsinyi yoo si “duro titi laelae.” (Danieli 2:44) Ni ọ̀nà yii Jesu, alaileeku ayanṣaṣoju ila idile ọlọba Dafidi naa, yoo wà pẹtiti gẹgẹ bi oṣupa, “ẹlẹ́rìí otitọ ni ọ̀run.”
Fun idi yii, ni gbogbo ìgbà ti o bá rii ti oṣupa ń tan rokoso lalẹ loju ọrun, ranti ileri Ọlọrun fun Dafidi ki o sì ṣọpẹ́ pe Ijọba Ọlọrun ń ṣakoso nisinsinyi yoo si ṣakoso titilae, si ogo Ọlọrun ati si ibukun ayeraye iran eniyan oluṣotitọ.—Ìfihàn 11:15.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Frank Zullo