-
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
4. Kí ni Jèhófà máa ń rántí nípa àwa èèyàn, báwo lèyí ṣe kan bó ṣe ń ṣe sí wa?
4 Jèhófà kì í retí ohun tó kọjá agbára wa. Sáàmù 103:14 sọ pé: “Ó mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” Jèhófà máa ń rántí pé erùpẹ̀ lòun fi dá wa, ó sì mọ̀ pé a lè ṣàṣìṣe nígbà míì torí pé aláìpé ni wá. Gbólóhùn náà ó mọ “ẹ̀dá wa” rán wa létí pé Jèhófà dà bí amọ̀kòkò, a sì dà bí amọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Jeremáyà 18:2-6) Bóyá a yàn láti ṣe ohun tó tọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, Jèhófà máa ń fòye bá gbogbo wa lò torí pé ó mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá kò sì rọrùn fún wa láti ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́ ní gbogbo ìgbà.
-
-
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
1-3. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì lẹ́yìn tó dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ló mú kára tù ú? (b) Kí ló ṣeé ṣe ká máa rò lẹ́yìn tá a bá dẹ́ṣẹ̀, àmọ́ kí ni Jèhófà sọ tó fi wá lọ́kàn balẹ̀?
-