-
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́runGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
2. Tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́, àwọn àṣà wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?
Bíbélì sọ fún wa pé ká “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká máa sá fún ohunkóhun tó lè ba ara àti ọpọlọ wa jẹ́. Ó yẹ kí ohun tá à ń rò máa múnú Jèhófà dùn, torí náà a gbọ́dọ̀ máa sapá gan-an láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn wa. (Sáàmù 104:34) Bákan náà, kò yẹ ká máa sọ ọ̀rọ̀ rírùn.—Ka Kólósè 3:8.
Báwo la ṣe lè máa jẹ́ mímọ́ nípa tara, nínú èrò wa, ìwà wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa? Àwọn nǹkan kan wà tó lè kó ẹ̀gbin bá ara wa. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa mu sìgá, igbó tàbí tábà, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa lo oògùn olóró. Tá a bá ń yẹra fáwọn nǹkan yìí, a ò ní sọ ara wa di ẹlẹ́gbin, èyí á sì fi hàn pé a mọyì ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wa. Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà jẹ́ mímọ́ ni pé ká má ṣe máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wa, ká má sì máa wo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe. (Sáàmù 119:37; Éfésù 5:5) Òótọ́ ni pé kò rọrùn rárá láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà yìí, àmọ́ Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè jáwọ́.—Ka Àìsáyà 41:13.
-
-
Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Lójú Ọlọ́runGbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
-
-
5. Máa sapá kó o lè borí èrò àti àṣà tí kò dáa
Ka Kólósè 3:5, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Báwo la ṣe mọ̀ pé wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe, fífi ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí fóònù àti fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni jẹ́ ohun ẹlẹ́gbin lójú Jèhófà?
Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé ká jẹ́ mímọ́ nínú èrò wa, ọ̀rọ̀ wa àti ìṣe wa? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
Wo fídíò yìí kó o lè mọ bó o ṣe lè borí èrò tí kò dáa. Wo FÍDÍÒ yìí.
Jésù lo àpèjúwe kan láti jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ jẹ́ mímọ́ nínú èrò, ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, àfi ká máa sapá gidigidi. Ka Mátíù 5:29, 30, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Kì í ṣe pé Jésù ń sọ pé ká ṣe ara wa léṣe o, àmọ́ ohun tó ń sọ ni pé tá a bá fẹ́ máa jẹ́ mímọ́ lérò, lọ́rọ̀ àti níṣe, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó lágbára. Ìgbésẹ̀ tó lágbára wo lo rò pé ẹnì kan lè gbé kó má bàa gba èrò tí kò dáa láyè nínú ọkàn ẹ?b
Jèhófà mọyì gbogbo bó o ṣe ń sapá gidigidi láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn. Ka Sáàmù 103:13, 14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Tó o bá ń sapá láti gbé èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn, báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀?
Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ!
O lè máa ronú pé, ‘Mi ò rò pé mo lè jáwọ́ nínú àṣà yìí jàre, bóyá kí n kúkú gba kámú.’ Àmọ́, rò ó wò ná: Tí sárésáré kan bá fẹsẹ̀ kọ tó sì ṣubú, kò túmọ̀ sí pé ó ti pàdánù nìyẹn, kò sì ní torí ìyẹn wá lọ bẹ̀rẹ̀ èrè náà pa dà látìbẹ̀rẹ̀. Lọ́nà kan náà, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o tún jìn sọ́fìn àṣà tó ò ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú ẹ̀, kò túmọ̀ sí pé o ti pàdánù nìyẹn. Bákan náà, ìyẹn ò fi hàn pé asán ni gbogbo ìgbìyànjú ẹ àtọjọ́ yìí. Fi sọ́kàn pé tó o bá ṣubú, ńṣe ló yẹ kó o dìde. Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ! Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí ò dáa.
-