ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Olódodo Yóò Máa Yin Ọlọ́run Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́—2009 | March 15
    • 11, 12. Àwọn ọ̀nà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run gbà ń lo àwọn ohun ìní wọn?

      11 Àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti fi hàn pé ọ̀làwọ́ làwọn nípa tara. Sáàmù 112:9 sọ pé: “Ó ti pín nǹkan fúnni lọ́nà gbígbòòrò; ó ti fún àwọn òtòṣì.” Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ sábà máa ń dá nǹkan jọ fáwọn Kristẹni bíi tiwọn tó bá di aláìní, kódà wọ́n máa ń ṣe irú ẹ̀ fáwọn aládùúgbò wọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tún máa ń fi àwọn nǹkan ìní tara ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìrànwọ́ tí wọ́n máa ń ṣe fáwọn èèyàn lásìkò àjálù. Gẹ́gẹ́ bí Jésù sì ṣe sọ, ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ń fún wọn ní ayọ̀ pẹ̀lú.—Ka Ìṣe 20:35; 2 Kọ́ríńtì 9:7.

      12 Láfikún sí i, ronú nípa iye owó tí ètò Ọlọ́run ń ná láti máa tẹ ìwé ìròyìn yìí ní èdè méjìléláàádọ́sàn-án [172], tó sì jẹ́ pé àwọn tí nǹkan ò rọ̀ṣọ̀mù fún ló ń sọ púpọ̀ nínú àwọn èdè náà. Ohun tó tún yẹ fún àkíyèsí ni pé ìwé ìròyìn yìí tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití, a sì tún ń ṣe èyí táwọn afọ́jú lè kà.

  • Àwọn Olódodo Yóò Máa Yin Ọlọ́run Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́—2009 | March 15
    • ‘A Fi Ògo Gbé E Ga’

      17. Báwo ni a ó ṣe “fi ògo gbé” olódodo “ga”?

      17 Ẹ wo bí yóò ti dùn tó nígbà tí gbogbo wa pátá bá jọ ń yin Jèhófà láìsí àtakò kankan látọ̀dọ̀ Èṣù àti ayé rẹ̀! Títí ayé ni gbogbo àwọn tí Ọlọ́run bá kà sí olódodo yóò sì máa fi irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀ yìn ín. Ìtìjú ò ní dorí wọn kodò, àwọn ọ̀tá ò sì ní borí wọn, níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣèlérí pé “ìwo” ìránṣẹ́ òun olódodo ni ‘a ó fi ògo gbé ga.’ (Sm. 112:9) Ìránṣẹ́ Jèhófà olódodo yóò yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun nígbà tó bá rí ìparun gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọba Aláṣẹ.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́