-
“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”Ilé Ìṣọ́—2000 | May 15
-
-
Nígbà tí Sólómọ́nì ń rántí ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí baba rẹ̀ fún un, ó sọ pé: “Baba mi a sì máa fún mi ní ìtọ́ni, a sì máa wí fún mi pé: ‘Ǹjẹ́ kí ọkàn-àyà rẹ di àwọn ọ̀rọ̀ mi mú ṣinṣin. Pa àwọn àṣẹ mi mọ́ kí o sì máa bá a lọ ní wíwà láàyè. Ní ọgbọ́n, ní òye. Má gbàgbé, má sì yà kúrò nínú àwọn àsọjáde ẹnu mi. Má fi í [ọgbọ́n] sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ. Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye.’”—Òwe 4:4-7.
-
-
“Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọkàn-àyà Rẹ”Ilé Ìṣọ́—2000 | May 15
-
-
Ó tún pọndandan láti ni òye. Láìsí òye, ǹjẹ́ a lè rí i bí àwọn kókó kọ̀ọ̀kan ṣe so mọ́ ara wọn ní ti gidi, kí a sì wá mọ bí ọ̀ràn tí a ń gbé yẹ̀ wò náà ṣe rí gan-an? Bí a kò bá ní òye, báwo la ṣe lè mọ ìdí àti ète tí àwọn nǹkan fi ṣẹlẹ̀, kí a sì wá ní ìjìnlẹ̀ òye àti ìfòyemọ̀? Lóòótọ́, ká tó lè jókòó, ká ronú jinlẹ̀ kí a sì wá ṣe ìpinnu tó tọ́, a nílò òye.—Dáníẹ́lì 9:22, 23.
-