ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí
    Ilé Ìṣọ́—1999 | September 15
    • A ṣàlàyé ète táa fi kọ ìwé Òwe nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Òwe Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí, láti fi òye mọ àwọn àsọjáde òye, láti gba ìbáwí tí ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye, òdodo àti ìdájọ́ àti ìdúróṣánṣán, láti fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà, láti fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.”—Òwe 1:1-4.

  • Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí
    Ilé Ìṣọ́—1999 | September 15
    • Onírúurú ànímọ́ ló para pọ̀ jẹ́ ọgbọ́n, lára rẹ̀ ni òye, àròjinlẹ̀, lílo làákàyè, àti agbára láti ronú. Òye ni agbára àtiyẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀ràn wò, kí a sì mọ bó ṣe rí nípa wíwo gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ọn, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ lóye rẹ̀. Àròjinlẹ̀ ń béèrè pé ká ní agbára àtironú lórí nǹkan, ká sì mọ ìdí tí ọ̀nà kan fi tọ́ tàbí tó fi burú. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó lóye lè mọ ìgbà tí ẹnì kan bá ń forí lé ọ̀nà tí kò tọ́, ó sì lè tètè kìlọ̀ fún onítọ̀hún pé ewú wà níbẹ̀. Àmọ́, ó gbọ́dọ̀ ní àròjinlẹ̀ kó tó lè mọ ìdí tí onítọ̀hún fi forí lé ọ̀nà yẹn, kí ó sì wá ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tó fi lé gba ẹ̀mí rẹ̀ là.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́