ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | November 15
    • Sólómọ́nì ròyìn pé: “Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn, bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa, àti gan-an gẹ́gẹ́ bí pé a fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dì í fún ìbáwí òmùgọ̀ ènìyàn, títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ṣe kánkán sínú pańpẹ́, kò sì mọ̀ pé ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.”—Òwe 7:22, 23.

      Ìkésíni yẹn ti wọ ọ̀dọ́kùnrin yìí lára débi tí kò fi lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ó gbàgbé gbogbo agbára ìmòye rere pátá, gọ̀ọ́gọ̀ọ́ ló tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ‘bí akọ màlúù tó ń lọ fún pípa.’ Bí kò ṣe ṣeé ṣe fún ọkùnrin kan tí wọ́n kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí lẹ́sẹ̀ láti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́kùnrin náà di ẹni tí a fà sínú ẹ̀ṣẹ̀. Kò rí ewu tó wà nínú ẹ̀ rárá, “títí ọfà fi la ẹ̀dọ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,” ìyẹn túmọ̀ sí pé, àfìgbà tó gba ọgbẹ́ tó lè yọrí sí ikú rẹ̀. Ikú yẹn lè jẹ́ èyí tó ṣeé fojú rí nítorí pé ó ti ṣí ara rẹ̀ payá sí àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń fà èyí tí ń ṣekú pani.b Ọgbẹ́ yẹn tún lè fa ikú ẹ̀ nípa tẹ̀mí nítorí pé “ó wé mọ́ ọkàn òun gan-an.” Gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ̀ pátá ni ọ̀ràn náà nípa tó lágbára lé lórí, ó sì tún ti dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo sí Ọlọ́run. Ó tipa bẹ́ẹ̀ yára kánkán kó sínú ẹ̀mú ikú bí ẹyẹ kan tó kó sínú pańpẹ́!

  • “Pa Àwọn Àṣẹ Mi Mọ́ Kí o Sì Máa Bá a Lọ Ní Wíwà Láàyè”
    Ilé Ìṣọ́—2000 | November 15
    • b Àwọn àrùn kan tí ìbálòpọ̀ ń fà máa ń ba ẹ̀dọ̀ jẹ́. Fún àpẹẹrẹ, bí àrùn rẹ́kórẹ́kó bá ti lọ gogò tán, ńṣe làwọn kòkòrò àrùn yẹn máa bo ẹ̀dọ̀ pátápátá. Kòkòrò tó sì máa ń fa àtọ̀sí lè mú ẹ̀dọ̀ wú.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́