ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’
    Ilé Ìṣọ́—2001 | July 15
    • Olódodo tún ní irú ààbò kan tí olubi kò ní. “Ẹni tí ó bá ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àwọn ọ̀nà ara rẹ̀ ní wíwọ́ yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀. Ẹni tí ń ṣẹ́jú yóò ṣokùnfà ìrora, ẹni tí ó sì jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè rẹ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.”—Òwe 10:9, 10.

  • ‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’
    Ilé Ìṣọ́—2001 | July 15
    • Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ fẹ́ni tó di oníjìbìtì nítorí èrè onímọtara-ẹni-nìkan. Ẹlẹ́tàn lè gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ àrékérekè tàbí ìfarasọ̀rọ̀ tan àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa mọ̀ pé irọ́ lòun ń pa. (Òwe 6:12-14) Bó ṣe ń ṣẹ́jú wìíwìí, pẹ̀lú inú burúkú tàbí ètekéte, lè kó àwon tó tàn jẹ sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Àmọ́ bó pẹ́ bó yá, àṣírí ìwà màgòmágó rẹ̀ á tú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn kan a máa fara hàn gbangba, ní ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ ní tààràtà, ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú a máa fara hàn kedere lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn. Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, àwọn iṣẹ́ àtàtà a máa fara hàn gbangba, àwọn tí kò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò lè fi pa mọ́.” (1 Tímótì 5:24, 25) Ẹni yòówù kó máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀—ì báà jẹ́ òbí, ọ̀rẹ́, ọkọ tàbí aya ẹni, tàbí ojúlùmọ̀—kò lè mú un jẹ, àṣírí alábòsí náà máa tú ṣáá ni. Ta ló lè fọkàn tán alábòsí èèyàn?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́