-
Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Oníbìínú Èèyàn Bá Kò Mí Lójú?Jí!—2001 | December 8
-
-
“Inú ń bí i burúkú burúkú. Mo rò pé torí pé ó rí mi lọ́mọdé ló ṣe fẹ́ lù mí bolẹ̀. Bí mo ṣe ń tàdí mẹ́yìn ni mo ń sọ fún un pé: ‘Dúró ná! Tiẹ̀ ní sùúrù ná! Àní kó o dúró ná! Kí ló dé tó o fi fẹ́ lù mí ná? Mi ò ṣáà ṣe nǹkan kan fún ẹ. Mi ò tiẹ̀ mọ ohun tó ń bí ẹ nínú tó báyìí. Ṣé a lè jọ sọ ohun tó wà ńbẹ̀?’”—David, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún.
-
-
Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Oníbìínú Èèyàn Bá Kò Mí Lójú?Jí!—2001 | December 8
-
-
Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n yìí pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Òótọ́ ọ̀rọ̀, dídáhùn sí ìbínú pẹ̀lú “ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora,” á wulẹ̀ mú kí nǹkan burú sí i ni. Àmọ́ ṣá, lọ́pọ̀ ìgbà, dídáhùn lọ́nà pẹ̀lẹ́tù lè mú nǹkan rọlẹ̀ kó sì pẹ̀tù sí ìṣòro tó le koko náà.
Dá ọkàn rẹ padà sọ́dọ̀ David tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀. Ó bá ẹni tó fẹ́ lù ú bolẹ̀ náà sọ̀rọ̀ débi tíyẹn fi ṣàlàyé ohun tó ń bí i nínú. Ẹnì kan ló jí oúnjẹ ọ̀sán jàǹdùkú yìí gbé, ló bá fi ìkanra mọ́ ẹni tó kọ́kọ́ pàdé lọ́nà. David ṣàlàyé fún un pé: “Bó o bá nà mí, ìyẹn kọ́ ló máa dá oúnjẹ rẹ padà.” Ló bá sọ fún jàǹdùkú náà pé kó jẹ́ káwọn jọ lọ sí ilé oúnjẹ. David sọ pé: “Nítorí pé mo mọ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ rí, mó bá a wá oúnjẹ mìíràn. Ó bọ̀ mí lọ́wọ́, àtìgbà náà ló sì ti ń ṣe dáadáa sí mi.” Ǹjẹ́ o rí bí ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ṣe lágbára tó? Ìwé Òwe sọ ọ́ lọ́nà yìí pé, ‘ahọ́n pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lè fọ́ egungun.’—Òwe 25:15.
-