-
Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
-
-
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA ṢỌ́ Ọ̀RỌ̀ SỌ
4, 5. Báwo làwọn òwe kan nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká rí i pé ẹyin lohùn?
4 Ìdí pàtàkì kan tó fi yẹ ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ ni pé ẹyin lohùn. Òwe 15:4 sọ pé: “Ìparọ́rọ́ ahọ́n jẹ́ igi ìyè, ṣùgbọ́n ìfèrúyípo nínú rẹ̀ túmọ̀ sí ìrẹ̀wẹ̀sì nínú ẹ̀mí.”a Bí omi ṣe máa ń mú kí igi rúwé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ tá a fẹ̀sọ̀ sọ ṣe máa ń tu àwọn tó ń gbọ́ ọ lára. Àmọ́, òdìkejì gbáà ni ọ̀rọ̀ àyídáyidà tí ahọ́n ẹ̀tàn bá sọ, torí ńṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ ẹnu lè pani ó sì lè lani.—Òwe 18:21.
-